Wo ibi tí ọ̀rọ̀ gbígba béèlì Tani Ọlọ́rùn dé dúró

Aworan Tani Olohun

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun Facebook

Ile ẹjọ Majisireti, ti o fi ilu Ilọrin se ibujoko ti gbọ igbẹjọ lori gbigba oniduro tabi beeli gbajugbaja onisẹse ni Addulazeez Adegbola,Tani-Ọlọhun, to n jẹjọ niwaju rẹ.

Adajọ Muhammed Ibrahim to gbẹjọ lori ọrọ naa ti wa sunjọ igbẹjọ yi si ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹsan ọdun 2023.

Lọjọ yi ni yoo gbe idajọ ranpẹ kalẹ boya Tani Olohun lanfaani lati pada sile lẹyin ti agbẹjọro rẹ ba pari gbogbo ohn to yẹ ni ṣiṣẹ fn gbigba onidro rẹ.

Fun igba akọkọ, wọn ko gbe Tani Olọhun wa si ile ẹjọ sugbon awon agbejọro rẹ farahan lati ṣoju rẹ

Igbẹjọ yi ni akọkọ iru rẹ ti olujẹjọ naa ko ti yọju si ile ẹjọ ti wọn si gbọ ẹjọ rẹ lẹyin rẹ.

Awọn agbẹjọro rẹ ko so idi ti ko fi yọju sile ẹjọ bẹẹ si ni adajọ ko tako atotonu agbẹjọro nitori aisinibẹ Tani Olohun.

Ninu igbẹjọ naa, awon agbẹjọro Tani-Ọlọrun ti Ademọla Bank lewaju wọn parọwa sile ẹjọ pe ki wọn jọwọ onibara won nipa gbigba oniduro rẹ.

Awọn agbẹjọro ẹgbẹ Ogo Ilọrin ti o jẹ olupẹjọ ẹni ti Umar Imam saaju fun naa sọ tiwọn nipa ṣiṣe atako gbigba beeli rẹ yi.

Lẹyin ti Adajọ Muhammed Ibrahim ti gbọ awuyewuye awon agbẹjọro wonyi,o sun igbẹjọ lori beeli naa si ọjọ kọkandinlogun osu ti awa yii.

Bi o ba wu adajọ ni ọjọ naa o ṣeeṣe ki wọn gba gbogbo ẹbẹ wọle ki wọn si sọ ohun tawọn agbẹjọro gbọdo ṣe ki wọn to le tu Tani Olohun silẹ ko maa wa lati ile wa ṣe ẹjọ to ku.

Kini ofin sọ nipa ẹsun ti wọn fi kan Tani Olohun nipa beeli gbigba

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹjọro Tani Olohun lasiko to n ba awọn akọroyin takurọsọ ṣalaye pe ẹsun ti wọn fi kan Tani Olohun ko le debi pe wọn ko ni ṣe igbalaaye beeli gbigba rẹ.

Amofin Ademola Bank ṣalaye pe ọrọ beeli ko ka awọn laya bii ti pe wọn n jẹ ẹjọ Tani Olohun niwaju adajọ meji ọtọọtọ lori ẹsun kanna.

O ni ''ẹsun to ṣe gba beeli ni wọn fii kan bii ibanilorukọ,ilẹdi apo pọ ati dida omi alaafia ilu ru.Bẹẹli awọn nkan wọnyi ṣe e gba labẹ ofin.A kan n wo pe ko yẹ ko maa jẹjọ ẹsun kanna lọna meji ṣugbọn adajọ tako ibeere wa lori eyi.A o tẹsiwaju de ọjọ kọkandinlogun lati mọ ibi tọrọ ku si.''

O rọ awọn alatilẹyin Tani Olohun lati ṣe suuru ki wọn si ma hu iwa jagidijagan lori ọrọ igbẹjọ Tani Olohun.

Ọjọ kọkandinlogun yi ni wọn yoo gbe idajọ beeli kalẹ ni ileẹjọ Majistereeti ti wọn lọ lọjọ Iṣẹgun.

Ọjọ kan lẹyin ọjọ yi tii ṣe ogunjọ oṣu Kẹsan ni adajọ Upper Area naa sọ pe ki wọn pada wa lati wa bẹrẹ eto igbẹjọ beeli lori ẹsun pe o ba Alufa Okutagidi lorukọ jẹ.

Oníṣẹṣẹ Tani Olorun yóò tún fojú ba ilé ẹjọ́ míràn lónìí ní Kwara

Aworan Tani Olorun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Tani Olohun

Oniṣẹṣẹ Tani Olorun ti orukọ rẹ n jẹ Abdulazeez Adegbola yoo foju ba ile ẹjọ fun igba kejilaarin ọjọ meji.

Ana tii ṣe ọjọ Aje lo kọkọ foju ba ile ẹjọ Area Court 1 ni ilu Ilorin ni ipinle Kwara.

Igbẹjọ yi tawọn agbẹjọro rẹ pe lati gba idajọ eyi ti yoo paṣẹ pe ki ileẹjọ meji maa gbọ ẹjọ lori ẹsun kanna.

Awọn agbẹjọro rẹ lo pe ẹjọ yi ti wọn si tun sọ pe ile ẹjọ Area Court 1 ko kaju oṣunwọn lati gbẹjọ ibanilorukọje ti wọn fi kan Tani Olorun.

Amọ adajọ fi idi ọrọ mulẹ pe lootọ lawọn lẹtọ lati gbẹjọ yi nitori pe ọtọ lẹni to pe Tani Olorun lẹjọ to si yẹ ki awọn gbọ ẹsun ti wọn gbe wa si iwaju wọn.

Nibi igbẹjọ ranpẹ to waye lọjọ Aje bakan naa ni adajọ ti o wa ni Area Court 1 ti tun sọ pe ki wọn yi fi Tani Olorun si ahamọ titi di ọjọ ti wọn yoo fi gbẹjọ gbigba oniduro rẹ.

Ati agbẹjọro Tani Ọlọrun ati ti awọn olupẹjọ lo pada fẹnu ko si pe ki wọn pada wa sile ẹjọ lọsẹ to n bọ lati gbọ ẹjọ ranpẹ lori gbigba beeli rẹ lori ọkan ninu ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan an.

Ni oni tii ṣe ọjọ Iṣẹgun,igbẹjọ ti yoo waye leyi ti wọn yoo ṣe ni ile ẹjọ majistereeti ni Ilorin.

Igbẹjọ yi naa da lori ọrọ ibanilorukọjẹ.

Bẹẹ yoo tun da lori sisọ ọrọ to fẹ da ija ẹsin silẹ to si le fa wahala laarin awọn Oniṣẹṣe ati awọn Elesin Islam.

Awọn ogo Ilorin lo pe lẹjọ eleyi ni ile ẹjọ Majistereeti.

Ireti ni pe awọn agbẹjọro Tani Olorun yoo beere fun gbigba oniduro rẹ nile ẹjọ ki o baa le lanfaani lati lọ sile.

Ohun ti ko daju ni pe ti wn ba gba beeli rẹ ni ile ẹjọ kan, ṣe yoo si le pada sile nitori o ṣi wa niwaju ile ẹjọ mii to niki wọn fi si ahamọ titi di igba ti wọn yoo gbẹjọ beeli rẹ nibẹ.