Ẹbí, ọ̀rẹ́ barajẹ́ níbi ìsìnkú Remilekun tó kú sínú bàálù Egypt Airline

Oríṣun àwòrán, facebook
O jẹ akoko ibanujẹ fun awọn ẹbi, awọn ọrẹ ati awọn alabaṣiṣẹpọ ti wọn pejọ ni ipinlẹ Eko lati ṣẹyẹ ikẹyin fun Remilekun Toyosi Meshioye, ọmọ Naijiria to ku si ilẹ Egipti.
Ọjọ Kẹẹrin Oṣu Kẹsan Ọdun 2023 ni Remilekun ku sinu baalu ni Cairo, ti wọn si gbe wọ kaa ilẹ lọ nilu Eko.
Ninu ọrọ rẹ, Abdur-Rahman Balogun tii se agbẹnusọ fun ileesẹ to n mojuto awn ọmọ Naijiria to wa nilẹ okeere (NIDCOM) lo soju fun oludari ajọ naa, Abike Dabiri-Erewa.
Dabiri wa rọ gbogbo ẹbi lati mọkan to si tun fi kun pe “Ọrọ nikan ko le pa irora ti iku rẹ ti mu wa si idile”.
Bakan naa, Olusoagutan Aguntan Seyi Elliott sọrọ iyanju nibi iboju oloogbe naa.
O ni bo tilẹ jẹ pe igbesi aye Remilekun ti kuru, sugbọn o yẹ ki gbogbo eniyan mọ pe o gbe igbe aye ifọkanbalẹ ni tootọ.
"O dun wa lọpọlọpọ wi pe a padanu iru eeyan bayi sugbọn ko si ohun ti a le se niru akoko bayii."
Ẹni to jẹ ẹgbọn ologbe iyafin Funmi Oluwakemi Shilgba, ẹniti o dari eto isinku naa, sọ pe Remilekun jẹ eeyan ti o kun fun igbagbọ ati ọgbọn, ti o si jẹ ẹnikan to ṣetan lati ran awọn ẹlomiiran lọwọ.
Awọn ọrẹ, awọn alabasiṣẹpọ ati awọn mọlẹẹbi oloogbe naa ẹni ti o ni aanu ati ọkan to dara si gbogbo eeyan ni alaisi naa.
"O dun wa lọpọlọpọ wi pe a padanu iru eeyan bayi sugbọn ko si ohun ti a le se niru akoko bayii."
Eto isinku ọlọjọ mẹta fun Remilekun lo bẹrẹ pẹlu gbigba ara ologbe naa lati ilu Cairo, wa si papa ọkọ ofurufu Muritala Muhammad to wa ilu Eko.
Ti ara ologbe naa si wọ kaalẹ ni itẹ oku to wa ni Ladipo nitosi Oshodi nilu Eko lẹhin lẹyin isin ranpẹ lẹgbẹ iboji.
Bẹẹ gba gbagbe, awọn ẹbi pinnu lati gbe ara ologbe naa pada wa si ile fun isinku lẹhin awọn alakoso ileesẹ ọkọ ofurufu Egypt ti gba lati se gbogbo ojuse to yẹ.

Oríṣun àwòrán, facebook














