Kà nípa ọkùnrin ayọ́runbọ̀ tí ọkọ̀ ojú irin wọ́ nílẹ̀ turutu àmọ́ tí àwọn áńgẹ́lì ṣe ìwòsàn fún

Awonran David Ditchfield

Oríṣun àwòrán, Janet Reindorf

    • Author, Vishva Samani
    • Role, BBC World Service

David Ditchfield jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlelọgọta, to si jẹ ọmuti to n mu amu para.

Ọdun 2006 ni igbesi aye rẹ ni Ilu London ko lọ bo ṣe yẹ ko lọ

Lasiko ti nnkan safẹrẹ diẹ yii, David fẹ duro ti ẹgbọn rẹ obinrin ni olu-ilu ni Cambridgeshire.

Ọkan lara awọn ọrẹ wa lati ṣabẹwo sì, bi David se n sin ọrẹ rẹ naa lọ ibudo ọkọ reluwe, bo ṣe n sọ pe odabo, ẹwu kootu rẹ ha mọ ẹnu ilẹkun ọkọ reluwe.

O n wọ nilẹ pẹlu reluwe to n lọ, to si fìdí janlẹ loju opopona naa, eyi to fa ọpọlọpọ egbo si ni ara, ti apa rẹ kan si da.

Ki wọn to gbe David lọ si ile iwọsan fun isẹ abẹ, o ni iriri ati adiitu to ya ni lẹnu

O ni "Mo fi ara mi silẹ. Mo kuro nibi rogbodiyan ile iwosan. Mo fi gbogbo irora to n da ago ara mi laamu , ti mo wa ni aaye ti o dakẹ.”

"Nigba ti mo wo oke, mo ri awọn ila mẹta ti wọn funfun ti o rọra sun mọ mi. O jẹ nkan to n dan lara ṣugbọn o jẹ mimọ ti mi o le wo inu rẹ. Ti mo si n ri bi ina ṣe n wọ inu ara mi, to si n ṣe iwosan fun mi. Eyi to mumi larada"

David tun ni iriri nipa awọn angẹli to ṣabẹwo si i.

O ni "O da bii pe wọn n ṣe iwosan si gbogbo awọn ọgbẹ ara mi, ti wọn si n pa gbogbo awọn apẹẹrẹ ipalara rẹ ninu igbesi aye mi.

Fun igba akọkọ mo ri pe mo tiraka lori ọna lati pada si aye.

Aworan ise David Ditchfield

Oríṣun àwòrán, David Ditchfield

Ṣugbọn ipa to kẹyin ninu iriri David to ṣe pataki ju, eyii to ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi pe oun wa laarin awọn irawọ,

"Mo ri pe gbogbo iṣan mi n gbọn pẹlu agbara lati inu oju eefin funfun naa. Mo n wo orisun gbogbo ẹda. Inu mi kun fun ayọ."

Lai ni eyikeyi iriri nipa orin kikọ ṣaaju, David kọ awọn orin aladun pẹlu aworan to safihan awọn iriri rẹ lasiko nnkan to sẹlẹ si.

Awọn akopọ awọn orin rẹ ni wọn kọ sita ni agbegbe rẹ ti ọkan ninu awọn aworan rẹ si wa ni ifihan lọwọlọwọ ni ile ti wọn n ko awọn ohun iṣembaye si niluu Washington, nilẹ Amẹrika.

Sibẹsibẹ, David ko ka irinajo rẹ si pe o jẹ iriri ẹsin bikoṣe eyii to n sapejuwe ara rẹ gẹgẹ bii ẹni ẹmi.

Iriri Ajinde

Dokita Steve Taylor to jẹ onimọ ijinlẹ awọn ohun ti ẹmi sọ pe irufẹ ti David ri jẹ ohun iyalẹnu ti ko wọnpọ.

“Nigbati o ba ni iriri iku to sun mọ ọ, o jẹ ohun iyalẹnu to ni agbara gidi.”

Taylor, to jẹ olukọni agba ni ile ẹkọ giga Leeds Beckett sọ pe “O maa n waye si awọn eeyan to ni oju iwoye alailẹsin.”

David Ditchfield niwaju piano

Oríṣun àwòrán, Janet Reindorf

O ni awọn kan maa n tumọ iru awọn iriri bẹẹ lọna ẹsin, amọ nigba mii kii ri bẹẹ.

Iwadii sayẹnsi to ṣalaye pe awọn iṣẹlẹ to n mu eeyan sumọ iku maa n waye lasiko ti atẹgun ko ba ra ye wọ inu ọpọlọ tí eeyan ba wa ni ipo to sumọ iku.

Gigi Strehle, to jẹ oṣere lati ariwa London to kudię ko padanu ẹmi rẹ ni ile-iwosan sọ pe aini atilẹyin lati jiroro iru awọn iriri bẹ jẹ ohun to lagbara lati fidi rẹ mulẹ.

Gigi Strehler

Oríṣun àwòrán, Henrietta Garden

Àkọlé àwòrán, Gigi Strehler