A ṣetán láti ṣàtìlẹ́yìn ìjóba Tinubu fún ìlọsíwájú Naijiria – Labour Party

Bola Tinubu/peter Obi

Oríṣun àwòrán, Facebook: Bola Tinubu/Peter Obi

Igun ẹgbẹ oṣelu Labour Party, ti Lamidi Apapa n dari ti ki Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ku oriire bo ṣe jawe olubori ninu eto idibo to gbe e wọle.

Igun ẹgbẹ ọhun tun sọrọ kobakungbe si oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ ninu idibo ọdun 2023, Peter Obi.

Ẹgbẹ oṣelu Labour tun fidi rẹ mulẹ wi pe ko si magomago ninu eto idibo to gbe Tinubu wọle gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria, to si ni awọn ti ṣetan lati darapọ mọ ijọba rẹ fun ilọsiwaju Naijiria.

Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Abayọmi Arabambi gbe jade lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023, lo ti fi ọrọ naa lede.

O sọ pe o di dandan lati jawọ ninu gbogbo rogbodiyan to wa nilẹ niwọn igba ti idajọ ododo ti waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2023.

Siwaju sii ni Arabamba to ti figba kan ri jẹ alaga ẹgbẹ Labour nipinlẹ Ogun tun fi kun ọrọ rẹ pe Aarẹ Tinubu yẹ fun ipo to wa, nitori to ti ṣiṣẹ takuntakun sẹyin.

Wọnyi ni awọn koko pataki mẹfa to jẹyọ ninu atẹjade ọhun

Ẹgbẹ oṣelu Labour ki Aarẹ Bọla Tinubu ku oriire lori idajọ to waye lori idibo apapọ ọdun 2023.

Labour Party ni idajọ ododo to waye ti fi opin si gbogbo rogbodiyan to jẹyọ latari idibo apapọ to waye lọjọ kẹẹdogun, oṣu keji, ọdun 2023.

Ẹgbẹ naa bu ẹnu atẹ lu Peter Obi ati igibmọ agbẹjoro lori gbigbe ẹsun to ko lẹsẹ nilẹ lọ sile ẹjọ, o fin ku pe ẹjọ naa lo ku diẹ kaato ju ninu itan orileede Naijiria

O sọ siwaju si pe alaga ẹgbẹ naa patapata, Bashiru Lamidi Apapa ati gbogbo ọmọ igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ ṣetan lati ba Tinubu ṣiṣẹ papọ fun ilọsiwaju Naijiria.

Ẹgbẹ oṣelu Labour oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar gbiyanju agbara rẹ lati di Aarẹ orileede yiii, ṣugbọn ayanmọ rẹ ko rọ mọ, ati pe awọn ki oun naa ku oriire ọkan akikanju to ni lati ṣakoso Naijiria.

Egbẹ ọhun warọ gbogbo awọn to n fi apa janu, yala araalu tabi awọn ẹgbẹ alatako lati gba kamu, nitori pe ko si nnkan ti wọn tun le ṣe mọ, bi ko ṣe pe ki wọn gbaruku ti Aarẹ Tinubu fun itẹsiwaju.