Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí èèyàn 32, ọ̀pọ̀ farapa

Aworan afihan ijamba ọkọ

O kere tan eeyan mejilelọgbọn lo ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba oju popo nibi ti ọpọ ọkọ ti kọlu ara wọn ni Egypt.

Ileeṣẹ ilera orileede naa lo fidi ọrọ yi mulẹ.

Ijamba ọkọ yi waye lowurọ ọjọ Abamẹta ni agbegbe Beheira to wa loju popo Cairo-Alexandria to wa ni iwọn mẹẹli mejilelọgọrin si ariwa olu ilu ilẹ naa,Cairo.

Awọn ti ileeṣẹ ilera lo farapa jẹ nkan bi eeyan mẹtalelọgọta.

Ileeṣẹ iwe iroyin Al-Ahram jabọ pe ọkọ akero kan ati awọn ọkọ miran lo farakasa iṣẹlẹ yi.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi awọn kan gbana ninu awọn ọkọ wọnyii.

Pupọ awọn to si padanu ẹmi wọn la gbọ pe wọn jona doju iku ninu ijamba yi.

O kere tan ọkọ ako alaarẹ taa m si ambulansi ogun ni wọn fi ranṣẹ si ibi ti ijamba yi ti waye gẹgẹ bi ileeṣẹ ilera ṣe sọ ninu atẹjade kan.

Minisita feto ilera Dokita Khaled Abdel Ghaffar sọ pe awọn ti gbe awọn to farapa lọ si ileewosanWadi al-Natrun, ti wọn si ko awọn mii lọ si ileewosan Al-Nubaria.

Ijamba ọkọ a maa saba waye ni Egypt.

Ọpọ oju ọna ni ko si ni ipo alaafia ti awọn awakọ naa a si tun maa kọti ikun si ofin irina loju popo.

Aworan afihan ibi ti ijamba ọkọ yi ti waye.