Èèyàn méjì jáde láyé lẹ́yìn tí bàbá mọ́ọ̀mọ̀ fún ọmọ rẹ̀ ní bisikíìtì tí wọ́n fí májèlé sí

Aworan afihan bisikiiti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ọlọpaa lagbegbe Limpopo lorileede South Africa ti bẹrẹ iwadii lati mọ ohun to ṣokunfa iku arakunrin ẹni ọdun mọkandinlagoji ati ọmọ rẹ ọdun marun un ti iroyin ni wọn padanu ẹmi wọn.

Pipadanu ẹmi nikan kọ bi kii ṣe pe wọn lawọn mejeeji jẹ bisikiiti ti wọn fi majele si.

Iṣẹlẹ yi waye lọjọ Ẹti ni adugbo Extension 6 ni Bela-Bela.

Orukọ awọn oloogbe naa ni Mpho Lefoka iyẹn ọmọ ọdun marun un ati baba rẹ Tshepo Koos Ramotsho.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Hlulani Mashaba sọ pe iwadii ibẹrẹ fi han pe ija lile kan waye laarin arakunrin yi ati ọrebinrin rẹ lowurọ ọjọ iṣẹlẹ yi.

Mashaba sọ pe nigba ti yoo fi di ọwọ ọsan,baba ọmọ yi lọ mu ọmọ rẹ ni ileẹkọ jẹleosinmi to wa to si da pada sọdọ iya rẹ.

''Ko pẹ pupọ ti ọmọde yi bẹrẹ si ni kerora pe in u n run oun to si sọ fun iya rẹ pe baba oun lo fun oun ni bisikiiti jẹ.Iya ọm yi sare gbe lọ si ileewosan to wa ni itosi ṣugbọn o padanu ẹmi rẹ nigba ti yoo fi de ibẹ''

Baba jẹwọ pe oun fun ọmọ rẹ ni bisikiiti to ni majele

Ko pẹ si igba ti iroyin iku ọmọ yi lu sita lawọn olugbe araadugbo Extension 6 yi ko ara wọn jọ lati lọ da sẹria fun baba ọmọ to ku.

Ọpẹlọpẹ awọn agbofinro to da wọn lọna ti wọn si mu ọrọ to ti fẹ maa ru bi omi gbona walẹ lọkan wọn.

A gbọ pe baba ọmọ yi naa gba ile iwosan lọ toun naa si n ke irora pe inu n run un.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ ọlọpaa ṣe wi, ''baba ọmọ yi sọ fun awọn oṣiṣẹ ilera to ba nibẹ pe oun mọọmọ fi majele si bisikiiti toun ati ọmọ oun jijọ jẹ.''

''Wọn ṣe itọju baba naa ni ile iwosan alabẹle ki wọn to wa gbe pada lọ si ile iwosan Bela-Bela amọ nigba ti yoo fi de ibẹ, awn dokita kede pe o ti gbẹmi mi''

Kọmiṣana ọlọpaa lagbegbe ti iṣẹlẹ yi ti waye Lt-Gen Thembi Hadebe, parọwa si awọn lọkọ laya ti ede aiyede baa n waye laarin wọn lati kan si awọn to le gba wọn ni imọran ti yoo yanju aawọ wọn.

O ni o ṣeeṣe ki iru iṣẹlẹ buruku yi ma waye ka ni wọn tọ awọn ti yoo gba wọn ni imọran lọ.

Alukoro ọlọpaa sọ pe awọn yoo tẹsiwaju ẹkunrẹrẹ iwadii lati le fidi ọrọ iṣẹlẹ naa mulẹ