Orí ‘Dating App’ tí mo dá sílẹ̀ ni mo ti pàdé ìyàwó mi- Ọkùnrin tó fi iṣẹ́ olùṣirò owó sílẹ̀ di alárinà

Àkọlé fídíò, Orí ‘datin app’ tí mo dá sílẹ̀ ni mo ti pàdé ìyàwó mi -
Orí ‘Dating App’ tí mo dá sílẹ̀ ni mo ti pàdé ìyàwó mi- Ọkùnrin tó fi iṣẹ́ olùṣirò owó sílẹ̀ di alárinà
Aworan Dare Olatoye ati aya re.

Oríṣun àwòrán, Dare Olatoye

Ọkunrin to jẹ akọmọṣẹ oluṣiro amọ to pada di alarena, Dare Olatoye ti ṣalaye fun BBC Yoruba bo ṣe pade iyawo rẹ lori aapu to ti n gbe ọkọ ati aya fun awọn eeyan.

Iṣẹ oluṣiro ni Olatoye n ṣe nileeṣẹ kan to n ri si ọrọ epo rọbi ko to ya bara sidi iṣẹ alarena.

Gẹgẹ bii ohun to sọ fun BBC, ọpọ owo ni ọkunrin naa n pa loṣoṣu amọ ko ni ayọ nidi iṣẹ naa.

O ni kii ṣe igba ti oun da aapu ti awọn ọdọ to ti balaga ti n pade ara wọn silẹ ni oun bẹrẹ iṣẹ alarena nitori o jẹ ohun ti n ti n ṣe tẹlẹ lati ile ẹkọ wa.

‘Bi mo ṣe bẹrẹ iṣẹ alarena loju paali’

Olatoye ni ẹgbọn oun kan to pade ọkọ rẹ lẹni ọdun mẹtadinlaadọta, ti ibi ti oun ati ọkunrin naa n gbe ko si ju iṣẹju mẹwaa sira wọn lọ lo fun oun ni iwuri lati mu iṣẹ naa lọkunkundun.

O ni “Emi naa wa wo pe awọn eeyan wọnyin ti pade ara wọn o, bawo ni a ṣe le ṣe aapu ti yoo jẹ ki awọn eeyan to n wa iyawo, to n wa ọkọ le tete ri ara wọn.”

“Ki ọrọ wọn ma da bii ti ẹgbọn mi to gba wọn ni ọdun mẹwaa ko to pade ọkọ rẹ ti ko dẹ jina si ọdọ rẹ., awa wo pe imọ ẹrọ le ṣe irufẹ nnkan bee.”

‘Ori Aapu gbọkọ-fun-wọn ti a ṣe ni mo ti pade iyawo mi’

Olatoye tẹsiwaju pe “Emi ni ẹni akọkọ to pade iyawo rẹ lori aapu naa... nigba ti mo wa nibẹ, emi naa n wa iyawo, mo dẹ ri iyawo nibẹ.”

“Laarin ọdun kan ti a pade ara ni a ṣe igbeyawo.”

O ni amala ati ẹran ogufe ni awọn mejeji jẹ nile oun nigba ti wọn kọkọ foju ganni ara wọn.

Olatoye

Oríṣun àwòrán, Ige Olabode Photography

“A ko gba awọn to n ṣe “hook-up” laaye lori Aapu wa’

Olaoye

Oríṣun àwòrán, bbc

Lori ọna ati gbogun ti iwa nọbi, o ni awọn ko gba awọn to n ṣiṣẹ nọbi laaye lori ẹrọ alarena naa.

“Ojojumọ ni a maa n yọ awọn eeyan kuro lori aapu wa lori ọrọ hooku-up.”

Olatoye ṣalaye pe ọpọ aṣeyọri ni ẹrọ gbọkọfunwọn naa ti ṣe latari bi awọn eeyan ṣe n pade ololufẹ wọn lori aapu naa ti wọn si n ṣe igbeyawo alarede loorekoore.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti Olatoye ba BBC Yoruba sọ.