Ọkùnrin kan wọ wàhálà nítorí àtẹ̀jíṣẹ́ ìfẹ́ tó fi ránṣẹ́ sí ìyàwó oníyàwó

Aworan ọlọpaa ati foonu

Oríṣun àwòrán, Ọlọpaa ati Ọwọ to mu foonu dani

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi oju ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji kan, Sikiru Oluwaṣeun Jamiu ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ijẹbu-Ode lori ẹsun wi pe o fi atẹjiṣẹ ifẹ ranṣẹ si iyawo oniyawo.

Ori ikanni ibara-ẹni sọrọ ti a mọ si Wasaapu ni wọn sọ pe Jamiu ti fi atẹjiṣẹ ifẹ naa ranṣẹ si Arabinrin Ọpẹyẹmi Adegbẹsan, eyi to bi ọkọ obinrin naa ninu.

Good Morning Babe” ni wọn sọ pe Jamiu fi ranṣẹ si obinrin naa ni nnkan bi aago mẹjọ aabọ aarọ kutu, lọjọ naa.

Ẹsun naa lo ka bayii pe “Iwọ Sikiru Oluwaṣeun Jamiu ‘ọkunrin’ lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan, ọdun 2021 ni nnkan bi aago mẹjọ kọja iṣẹju meji ladugbo Fidipọtẹ to wa niwaju ileeṣẹ IBEDC ni ijẹbu Ode, ayika ile-ẹjọ Majisireeti Ijẹbu-Ode.

“Wi pe o wuwa to tako alaafia igbeyawo to wa laarin Akintunde Adegbesan ati Ọpẹyẹmi Adegbesan nipa lilo ọrọ ‘Good Morning Babe’ lori ikanni Wasaapu 08059491562 ati 08138868837.

“Fun idi eyi, o ti ṣe si ofin to ni ijiya labala 249(d) ninu iwe ofin ọdaran ti ipinlẹ, ti ọdun 2006.”