Ẹ lọ fọkàn balẹ̀, a máa yanjú ọ̀rọ̀ àwọn Alálàájì ọmọ Nàìjíríà tí Saudi dá padà sílé - ìjọba

Aworan awọn alalaaji

Oríṣun àwòrán, nigeriahajjcom/X

Ijọba apapọ Naijiria ti ni kawọn alalaaji ti ijọba ilẹ Saudi Arabia wọgile fisa wọn lọ fọkanbalẹ, wọn lawọn yoo yanju iṣoro naa, ati pe iwadii ti bẹrẹ lori rẹ ni pẹrẹwu.

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni ijọba apapọ Naijiria fi ọrọ yii lede ninu atẹjade ti Francisca Omayuli, agbẹnusọ ajọ to n ri si irin-ajo ilẹ okeere nilẹ wa fi sita.

O ṣalaye pe ọkọ baaluu Air Peace to gbe awọn arin-rin ajo ti wọn fẹẹ lọọ ṣe Umurah ni Saudi naa, gbera pẹlu ero ẹrin-le-lọgọta -le-nigba (264), lati papakọ ofurufu Murtala Mohammed l’Ẹkoo ati ti Amimu Kano, wọn si balẹ si papakọ ofurufu King Abdul-Aziz ni Jeddah lọjọ kẹtala oṣu kọkanla yii.

Atẹjade naa sọ pe nigba tawọn arinrinjo naa de ibi ti wọn yoo ti sọkalẹ ni Saudi, awọn alaṣẹ ibẹ sọ fun wọn pe wọn ti fagile iwe irinna wọn, ati pe eeyan mẹta din ni ọgọsan-an (177) ni lati pada si Naijiria ninu wọn pẹlu ọkọ kan naa to gbe wọn wa.

Alalaaji mẹtadinlaadọrun-un ni wọn jẹ ko wọ Jeddah bi atẹjade naa ṣe wi, bẹẹ ni wọn sọ pe ijọba Saudi ko tii sọ idi kan fun igbesẹ yii.

Bakan naa ijọba Saudi ko tii sọ idi ti wọn fi fofin de arinrinajo mejidinlogun mii ni Saudi

‘’ Bo ṣe wu ko ri ṣaa, alajọṣe ọdun pipẹ ni Naijiria ti Saudi, a si ti ṣetan lati dena iru iṣẹle bayii ko ma baa waye mọ.

‘’ Fun idi eyi, a rọ gbogbo awọn alalaaji tọrọ naa kan lati fọkanbalẹ, ba a ṣe n yanju ọrọ naa lọwọ,'' Omayuli ṣalaye ninu atẹjade ti o fi sita.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Kí ló dé tí Saudi fi wọ́gilé físà alálàájì Nàìjíría 170 tó lọ fún Umrah?

O le ni aadọsan alalaji lati orileede Naijiria ti awọn alaṣẹ Saudi da pada ni kete ti wọn balẹ silẹ naa lati wa ṣe Umrah lọjọ Aje.

Gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin Naijiria ṣe jabọ, Saudi wọgile iwe irina wọn ti wọn si ni wọn ko ni le wọ ilẹ naa.

Iroyin naa sọ pe ọtalenigba ati mẹrin awọn arinrinajo fun iṣẹ ẹsin yi lo gbera lati ilu Kano ati Eko lọ si Saudi Arabia.

Ṣaaju ki wọn to gbera ni wọn ti ni awọn ti ṣayẹwo ti wọn si gba iwe irina fisa ki wọn to ko si baalu lọ si Saudi.

Amọ gbogbo fisa wọn gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni awọn alaṣẹ Saudi wọgile nigba ti wọn wa lori ofurufu.

Nigba ti wọn yoo fi balẹ, awọn alaṣẹ kọ lati jẹki wọn wọ ilẹ naa ti wọn si paṣẹ ki baalu Air Peace to gbe wọn gbera pada lọ si Naijiria.

Titi di akoko yi, awọn alaṣẹ Saudi ko ti sọrọ lori iṣẹlẹ yi.

Awọn arinrinajo ti ọrọ yii kan sọ fun awọn akọroyin Naijiria pe iyalẹnu lo jẹ fun awọn lati gbọ pe wọn wọgile fisa awọn nigba ti wọn balẹ.

Wọn ni gbogbo ohun to yẹ lawọn ṣe ki wọn baa le faaye gba awọn wọ orileede naa.

A gbọ pe Saudi pada faaye gba awọn arinrinajo mẹtadinlaadọrun ninu awọn arinrinajo yi lẹyin ti ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria ni Saudi da si ọrọ naa.

Amọ wọn da awọn mẹtadinlọgọsan to ku pada si Naijiria lalẹ ọjọ Aje.

Aarẹ Tinubu wa ni Saudi nigba ti iṣẹlẹ yi waye

Aworan Aarẹ Tinubu ati ọmọọba ilu Saudi

Oríṣun àwòrán, X/Bola Ahmed Tinubu

Lalẹ ọjọ Aje ti wọn da awọn alalaji yi pada si Naijiria, aarẹ Bola Tinubu ṣi wa ni Saudi nibi to ti n ṣe ipade pẹlu olori orileede naa nipa itẹsiwaju ibaṣepọ laarin Naijiria ati Saudi.

Lara ohun ti wọn sọ nibi ipade yi ni bi wọn yoo ṣe si oju ọna anfaani tuntun ati idokoowo laarin awọn mejeeji.

Ninu awọn orileede ti ọmọ ilẹ wọn a maa saba ṣe irinajo Hajj tabi Umrah lọ si Saudi ni Naijiria wa.

Koda aarẹ Tinubu naa kopa ninu Umrah lẹyin to pari ipade to ba lọ si Saudi.

A ko ti gbọ esi kankan yala lọdọ awọn alaṣẹ Saudi tabi ti Naijiria ohun ro ṣokunfa dida awọn ọmọ Naijiria yi pada wa sile.