Ìyanṣẹ́lódì ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò kan iná mọ̀nàmọ́ná, ojú òpó iná ọba pínpín kò dákú rárá -TCN

Aworan ifẹhonu awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ kan ati ibudo ipinna mọnamọna kan lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, NLC/TCN

Ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna lorilẹede Naijiria, TCN ti kede pe iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria to bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun ko di ipese ina mọnamọna lọwọ jakejado orilẹede Naijiria.

Ni owurọ ọjọ Iṣẹgun lawọn kan gbe iroyin jade pe opo ina mọnamọna apapọ lorilẹede Naijiria ti dẹnukọlẹ nitori iyanṣẹlodi naa ati pe okunkun birimu lawọn eeyan wa.

Amọṣa ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita, o ni ko si eera kankan to rin ipese ina mọnamọna lorilẹede Naijiria ati pe gbogbo awọn ojuko ipinna mọnamọna kaakiri Naijiri ni ina mọnamọna wa bayii fun pinpin kaakiri orilẹede Naijiria.

Aworan atẹjade ti ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna lorilẹede Naijiria fi sita.

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna kaakiri Naijiria TCN wa ni irọ patapata ni iroyin kan to n kiri lawọn iwe iroyin abẹle kan ni Naijiria pe ọkan lara awọn ọga agba ileeṣẹ naa kan ti sọ faraye pe ko ni si ina mọnamọna jakejado Naijiria lasiko iyanṣẹlodi naa.