Ọmọ Nàìjíríà, ẹ jẹ́ kí á padà sí iṣẹ́ àgbẹ̀ tí a bá fẹ́ gbé ọrọ̀-ajé wa dìde - Gbenga Daniel

Oríṣun àwòrán, Otunba Gbenga Daniel/Instagram
Ṣenẹtọ to n ṣoju Ila-Oorun ipinlẹ Ogun, Ọtunba Gbenga Daniel, ti gba awọn omọ Naijiria nimọran to ni yoo gbe ọrọ aje orilẹ-ede yii dide.
Otunba Daniel ni kawọn ọmọ Naijiria pada si iṣẹ agbẹ ti i ṣe iṣẹ ilẹ wa k’epo rọbi too de.
O ni anito ati aniṣẹku ounjẹ yoo wa, ọrọ-aje to doju delẹ yoo si dide.
Ọjọ Aje ọsẹ yii ni Daniel gbe imọran naa kalẹ nibi eto kan ti wọn ṣe fawọn agbẹ ọlọgbin irẹsi ni Ṣagamu,nibi ti wọn ti fun wọn leso irẹsi ti wọn le gbin ati ajilẹ.
Nigba to n ṣalaye siwaju, Sẹnetọ Daniel sọ pe o ṣe pataki fawọn eeyan lati bẹrẹ ọgbin, paapaa ti irẹsi. O ni eyi yoo mu kounjẹ pọ lorilẹ-ede yii, yoo tun jẹ ka le maa ta a sita lọpọ yanturu, eyi ti yoo ran ọrọ-aje Naijiria lọwọ.
Otunba Daniel ni ''mo fẹ rọ wa pe o ti to akoko fun wa lati pada si’ṣẹ agbẹ.
Ẹ jẹ ka bẹrẹ sii gbin irẹsi ka si sọ Naijiria di ọkan lara awọn orilẹ-ede to n pese irẹsi lagbaaye.
’’Oluwa ṣe wa loore ni Naijiria yii daadaa. Ko too di pe a ṣawari epo rọbi, ọpọlọpọ nnkan to le di ọrọ̀ fun wa la ni, iṣẹ agbẹ la si fi gbe ọrọ-aje wa duro ju ohunkohun lọ’’
Bi nnkan yoo ba tun pada sipo bii tatijọ, iṣẹ agbẹ lo le ṣe e gẹgẹ bi Gbenga Daniel to ti gomina Ogun fọdun mẹjọ ṣe sọ















