David Cameron, olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tẹ́lẹ̀ di Mínísítà tuntun f'ọrọ ókéré

Oríṣun àwòrán, David_Cameron
Iyipada to n waye labẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi ti ja si pe Olootu ijọba tẹlẹ David Cameron ti pada si ijọba lati wa di ipo Minisista ilẹ okere mu labẹ idari olootu ijọba Rishi Sunak.
Eyi ko sẹyin bi Olootu ijọba Sunak ṣe gba Minisita rẹ fọrọ abẹle Suella Braverman kuro nipo lori awọn ọrọ kan to sọ ni itako si ilana ijọba.
Suella to n lewaju ninu gbigbe ofin kalẹ ti yoo kọdi awọn arinrinajo lati wọ ilẹ Gẹẹsi , padanu iṣẹ rẹ latari ọrọ kan ti wọn lo kọ to si jade ninu iwe iroyin ‘The Times’ lỌjọbọ ọsẹ to kọja.
Ninu rẹ lo ti sọ awọn ọrọ kobakungbe kan lẹyin to ṣe afiwe awọn oluwọde to n gbe lẹyin Palestine gẹgẹ bi iwọde awọn janduku.
Wọn fi kun un pe apilẹkọ ti Braverman gbe jade ṣaaju iwọde naa da kun rogbodiyan to waye lasiko iwọde yii, bẹẹ ni wọn ni obinrin naa tun sọrọ abuku sawọn ọlọpaa to n ṣiṣe ki alaafia le jọba.
Braverman ni wọn lo koro oju si ohun to n ṣẹlẹ lọwọ ni Palestine, to si fi we iru eyi to ṣẹlẹ ni Ariwa Ireland.
Lati igba to si ti kọ ọrọ apilẹkọ rẹ ti wọn lo da wahala silẹ naa ni obinrin yii ti n koju atako, ki olootu ijọba too gba iṣẹ lọwọ rẹ laaarọ ọjọ Aje.
Iyipada ranpẹ yi tunmọ si pe Cameron ni yoo diipo Minisita fọrọ ilẹ okere mu ti ẹni to wa lori oye naa lọwọ iyẹn James Cleverly yoo si lọ rọpo arabinrin Braverman nipo Minisita ọrọ abẹle ti wọn ti yọ.
Igbesẹ yi jẹ ibẹrẹ atunto an ọmọ igbimọ ijọba Olootu Rishi Sunak.
A gbọ pe Therese Coffey naa ti fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi akọwe ọrọ ayika.
Agbẹnusọ Olootu ijọba sọ pe ''iyipada yi yoo fun Olootu lanfaani gbigbe igbimọ alaṣẹ ti wọn fimọ ṣọkan kalẹ eyi ti yoo jẹ ki wọn lke gbe ayipada daada ti orileede naa nilo lọjọ pipẹ''
Ninu esi rẹ si ikede rẹ gẹgẹ bi Minisita fọrọ ilẹ okere, David Cameron sọ loju opo rẹ ni Twitter pe ''lootọ ni mi o ti si ni ijọba laarin ọdun mẹfa si meje sẹyin amọ oye ati iriri ti mo ni yoo jẹ ki n le ṣatilẹyin fun olootu ijọba lati le koju awọn ipenija to wa niwaju yii''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ta ni Suella Braverman ti wọn yọ nipo Minisita abẹle?

Olootu ijọba tẹlẹ ni ilkẹ Gẹẹsi, Liz Truss, lo yan Arabinrin Braverman sipo gẹgẹ bi Minisita ọrọ abẹle loṣu kẹsan-an ọdun 2022.
Ṣugbọn arabinrin naa pada fipo yii silẹ nigba ti wọn lo fi ọrọ kan ranṣẹ loju opo ifọrọ-ranṣẹ (email) rẹ, eyi to lodi sofin nitori ohun to fi ranṣẹ naa ni i ṣe pẹlu ọrọ ilu.
Kete ti Rishi Sunak,Olootu ijọba to wa lori oye bayii bọ si ipo lo pe arabinrin Braverman pada sẹnu iṣẹ to si fori jin tohun ti pe ọran to lagbara lo da eyi to mu kọwe fipo silẹ.
Lagbo oṣelu ilẹ Gẹẹsi, Braverman jẹ eeyan kan ti ẹnu kii sin lara rẹ yala lori nkan to ba ṣe tabi ọrọ to ba sọ nipa aato ilu.
Ti ko ba maa sọrọ nipa awọn arinrinajo to n wa iṣẹ bọ wa si ilẹ Gẹẹsi lati ilẹ okere, yoo si maa sọ ọrọ ti ko bakun gbe nipa awọn to n ṣe iwọde tako nkan to n ṣẹlẹ lọwọ ni paapa ilẹ Palestine.
Ko tan sibẹ o tun tabuku iṣẹ tawọn ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi n ṣe nipa idaabo ilu ti eleyi si jẹ ọkan lara awọn ohun ti oloṣelu kii mẹnu ba ni ilẹ naa.
Atunto ati iyọnipo to ba tun kan yoo maa tẹsiwaju gẹgẹ bi a ṣe gbọ.













