Àjọ ICPC mú èèyàn mẹ́fà lórí ẹ̀sùn kátà-kárà ìbò, wọ́n gba N4.1m lọ́wọ́ wọn

Aworan owo

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Lasiko tawọn eeyan ipinlẹ Imo tu jade lati dibo yan gomina ti yoo tukọ ipinlẹ naa fọdun mẹrin mi-in lọjọ Satide, ọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun yii ni ajọ to n ri si iwakiwa atawọn ẹsun to ba jẹ mọ magomago, ICPC, nawọ gan-an eeyan mẹfa ti wọn fura si pe wọn fẹẹ fowo ra ibo lọwọ awọn oludibo, wọn si fọwọ ofin mu wọn lọgan.

Yatọ si pe wọn mu awọn eeyan naa, miliọnu mẹrin ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira o le (N4,101,750) ni wọn tun ba lọwọ wọn.

Ninu atẹjade ti ICPC fi sita lọjọ keji iṣẹlẹ yii ti i sẹ ọjọ Aiku, wọn ka ibudo ti wọn ti mu awọn afurasi naa, eyi ti i ṣe Abule Meko Orji, ileetura Concord, Rento, ileewe Township ati lle ikawe Ojukwu.

Atẹjade naa tẹsiwaju, pe awọn ẹṣọ ICPC ri iwe kan gba lọwọ ọkan lara awọn afurasi yii, nibi ti wọn kọ orukọ ati nọmba awọn oludibo si, pẹlu gbogbo akọsilẹ awọn oludibo naa.

''Gbogbo awọn afurasi tọwọ tẹ naa la fi sahaamọ nigba ta a mu wọn, a gba ọrọ ẹnu wọn silẹ lẹsẹẹsẹ.

A si ti fun wọn lanfaani beeli, iwadii n tẹsiwaju,'' ICPC ṣalaye.