Dá sẹ̀ríà fún adarí ilé-iṣẹ́ ìjọba tó bá kùnà láti kópa nínú ìjíròrò MTEF/FSP — Akpabio rọ Tinubu

Akpabio

Oríṣun àwòrán, @Akpabio

Aarẹ ile aṣofin agba ni Naijiria, Godswill Akpabio, ti wi pe ki Aarẹ Bola Tinubu fi imu adari ileeṣẹ ijọba ti o ba kọ lati yọju sibi ijiroro lori agbekalẹ iwoye inawo ijọba ọlọdun meji lati ọdun 2024 si 2026 ti wọn pe ni MTEF/FSP danrin.

Akpabio lo sọ ọrọ yii nibi iṣide ipade ijiroro naa nilu Abuja.

Aarẹ ile aṣofin naa wi pe adari ileeṣẹ ijọba to ba mọ ohun to n ṣe, to si tun nigbagbọ ninu aṣeyọri iṣejọba Aarẹ Tinubu ko ni firu ijiroro bẹẹ ṣere.

Ipade ọhun ni awọn igbimọ tẹẹkoto ile aṣofin naa lori eto inawo, iṣuna, iṣeto apapọ, ati ọrọ igbese nile-loko gbe kalẹ.

Akpabio rọ awọn to fẹẹ kopa ninu ijiroro ọhun lati sọ okodoro ọrọ nipa gbogbo ohun to nii ṣe pẹlu afojusun inawo ijọba naa.

“Ẹni ti ko ba gbe igbesẹ lati yege ti funra rẹ gbe igbesẹ lati kuna. Mo waa fi eyi ran awọn ọmọ igbimọ tẹẹkoto yii leti pe adari yowu to ba niran aṣeyọri ijọba Tinubu yoo yọju si ipade apero yii.

Mo fẹẹ ki alaga igbimọ tẹẹkoto eto inawo o fun mi ni orukọ awọn ti wọn fiwe pe ti ko yọju tori pe ibẹrẹ ijakulẹ wọn lẹnu iṣẹ ni eyi jẹ.

Ti a ba ri adari kankan to ba ran aṣoju wa, alaininkanṣe niru ẹni bẹẹ, o si yẹ ki Aarẹ Tinubu o ṣe ayẹwo iyansipo onitọhun.”

Akpabio wi pe eyi kii ṣe ihalẹ amọ ootọ ọrọ ni, nitori pe oun naa fi awọn apejọpọ miran bii aṣekagba ipolongo ibo ni Owerri silẹ lati darapọ mọ ijoko ọhun ni lojuna ati le jiroro lori itẹsiwaju ilẹ yii.

Aarẹ ile aṣofin naa, to juwe apejọpọ ọhun gẹgẹ bi eyi to lapẹẹrẹ nitori igba akọkọ niyi labẹ iṣejọba Tinubu, wi pe akoko apero naa lo nii ṣe pẹlu dida saa eto iṣuna pada saarin oṣu kini ọdun si oṣu kejila.