Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ògùn ayẹta mí kọ̀ láti sisẹ̀ - Babaláwo tó dán ògùn ayẹta lára oníbàárà

Danladi

Oríṣun àwòrán, Others

Babalawo Danladi Yau ti wa ni agọ ileeṣẹ ọlọpa nipinlẹ Bauchi lẹyin to yinbọn lu onibara rẹ kan to wa gba ogun ayẹta lọwọ rẹ.

Danladi ni asise ni isẹlẹ naa, to si jẹ pe igba akọkọ re ti irufẹ asise naa yoo tọwọ rẹ waye.

Danladi ni oun sọ sọ oloogbe Mohammed Ali lati mu adiye aye si ọwọ rẹ ki awọn fi dan ogun ayẹta naa wo pe ogun naa sisẹ sugbọn ibọn naa ṣesi ba Ali nikun.

Ninu fọnran ti Ileeṣẹ ọlọpaa Bauchi gbe sita lori ayelujara, Babalawo naa ni o ti pẹ ti oun ti n seto ogun ayẹta fun awọn eeyan to si jẹ igba akọkọ ree ti asise yoo waye.

Aworan ẹni to gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“Nigba ti wọn ba mi pe awọn fẹ ṣe ohun ayẹta, mo kọkọ ni ki wọn lo ra awọn nnkan lati lo, nnkan lati jẹ ẹlẹnu, ti awọn yooku si jẹ eyi ti wọn yoo fi simu.

“Nigba ti wọn pada de, mo bi wọn pe ṣe wọn ti ṣe gbogbo nnkan ti mo ni ki wọn ṣe, ti wọn si dami lohun pe bẹẹni pe ki a bẹrẹ isẹ . Koda, awọn ni wọn gbe ibọn wa.”

Oloogbe Ali jẹ olugbe Abule Damaiwa to wa ni ijọba ibilẹ Zaki nipinlẹ naa.

Ninu igbo Damaiwa ni Ali ati awọn ọrẹ mẹta ti lọ ba Babalawo Danladi ti lọ gba ogun ayẹta ibọn.

“Agbegbe ti wọn n gbe ni kudiẹkudiẹ nipa eto abo ni wọn fi fẹ lo ogun ayẹta ibọn ati ọbẹ,” Babalawo sọ ninu fọnran naa.

“Ninu ọkan mi, mo n ro pe awọn eeyan kan lo jẹ ki ileeṣẹ mi ja nitori gbogbo awọn ayẹta ti mo ti ṣe, ibọn ko le wọle , ka to wa ni a ṣekupa eeyan naa.”

Ki ni Ileeṣẹ Ọlọpaa sọ?

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Bauchi, Ahmed Wakil fidi isẹlẹ naa mulẹ to si ni awọn afurasi naa ti wa ni ihamọ.

Wakil ni bi awọn ṣe gbọ iro ibọn ni agbegbe naa ni awọn suure lọ sibẹ.

O ni ko si nnkan to jẹ mọ asise ninu ofin ilẹ Najiria, to si jẹ Babalawo yoo foju wina ofin.

“Ko si nnkan to jẹ asise ninu ofin ilẹ wa , ẹni to ba sẹ si ofin yoo foju wina ofin, a ti n gbaradi lati gbe Babalawo lọ si ile ẹjọ.

“Mo ti jẹ ọlọpaa fun ọpọlọpọ ọdun ti mọ si n sọ fun awọn eeyan pe ko si nnkan ti a n pe ni ogun ayẹta ibọn, to si jẹ pe irọ ni gbogbo to wa ni ita."

Ewé sunko,babaláwo yìnbọn pa Muhammed Ali níbi tí wọ́n ti ń dán ayẹta wò

Arakunrin ẹni ọdun mẹrinlelogoji kan ti kagbako iku nibi ti o ti tẹle babalawo ati awọn mẹta mii lọ dan ayẹta wo.

Ni abule Damaiwa lẹba Bursali ni ijọba ibilẹ Zaki niBauchi la gbọ pe Muhammadu Ali ti tọwọ ọta ibọn ku nigba ti wọn dan ayẹta wo lara rẹ.

Ohun ti wọn sọ fun ko to gbara duro ni pe ayẹta naa ko ni jẹ ki ọta ibọn wọle si lara.

Alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Bauchi Ahmed Wakili lofidi ọrọ yi mulẹ ninu atẹjade kan ti fi sọwọ sawọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun.

O ni kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ yi lawọn tara de ibẹ tawọn si gbe arakunrin naa digba lọ si ile iwosan.

O lo ṣeni laanu pe awọn dokita sọ pe o ti ku nigba ti wọn gbe de ọdọ wọn.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ọwọ ti ba afurasi meji ninu awọn ti wọn jijọ lọ sibẹ tawọn mii ninu wọn si na papa bora.

O ni awọn n tọ pinpin awọn iyoku to sa lọ yii.

Danladi lo ni ibọn ẹtu ti wọn fi dan ayẹta wo lara Muhammad Ali

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wakil to jẹ alukoro ọlọpaa ni Bauchi sọ pe ''Ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹwa ni nkan bi ago mẹjọ aabọ owurọ ni iro deti igbọ agọ ọlọpaa Bursali pe arakunrin kan Danladi Yau ẹni ọdun mejidinlọgbọn to wa lati abule Daimawa to si jẹ babalawo ati awọn mẹtaa mii toti na papa bora bayii jijọ lọ si inu igbo Daimawa lati lọ dan iṣẹ ayẹta wo lara Muhammadu Ali ti wọn jijọ wa lati abule kanna.''

O tẹsiwaju pe ''ibi ti wọn ti n dan iṣẹ yi wo ni ọta ibọn ti Danladi Ya'u rọ ti ba Muhammadu''

''Igba ti ọrọ naa de eti igbọ wa la gbe oloogbe Muhammadu lọ si ile iwosan nla Jakusko ni ipinlẹ Yobe.Nibẹ lawọn akọṣẹmọṣẹ oniṣẹ ilera ti sọ pe o dagbere faye.''

Iwadii gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa ti ṣe wi n tẹsiwaju ati pe awọn ti wọ awọn afurasi ti ọwọ tẹ lori ọrọ yi lọ siwaju ile ẹjọ.

Lafikun o ni awọn tun gburo pe afurasi adigunjale kan to tẹle awọn akẹgbẹ rẹ lọ ja awọn olugbe Bishop Moore Memorial School Staff Quarters ti pade iku lọwọ awọn araadugbo ti wọn gbaamu.

Ọrọ ayẹta ati igbagbọ awọn eeyan lori rẹ

Ninu igbagbọ ọpọ ẹya lorileede Naijiria ni paapa lọdọ awọn Yoruba, eeyan le fi ayẹta dena agbara ọta ibọn lara ti ko si ni ṣe eeyan ni nkan.

Igbagbọ yi to jẹ ohun tawọn agbaagba Yoruba a maa lo paapa awọn ọlọde lati fi kọdi awọn ole to ba wa pẹlu ibọn tabi awọn to ba fẹ kogun ja wọn, jẹ nkan ti a ko ribi fidi rẹ mulẹ pe o n ṣiṣẹ.

Ọlaju ati imọ sayẹnsi sọ di mimọ pe kii ṣiṣẹ ṣugbọn o yi ni awọn kan to gbagbọ pe ogun ti ko ba jẹ,ewe rẹ ni ko pe.

Lawọn abule ati oko, iroyin a maa jẹyọ lẹẹkọọkan nibi ti awọn to ba lọ dan iṣẹ ayẹta wo ba ti faragbọta tabi padanu ẹmi wọn.

Laipẹ la gbe iroyin bi ọmọde kan ṣe yinbọn pa aburo rẹ nigba ti wọn n dan ayẹta ti baba wọn gbe kalẹ wo.

A ko ri aridaju pe ayẹta n ṣiṣẹ tori naa awọn agbofinro kilọ fawọn eeyan lati sọra ṣe pẹlu awọn nkan ija oloro to le mu ẹmi lọ.