Ikú àwọn ọmọ wa obìnrin méjèèjí nínú ìkọlù Israel àti Palestine ló sọ wa dí ọ̀rẹ́ bí ọmọ ìyá- Bassam àti Rami

Oríṣun àwòrán, Rami Elhanan
- Author, Suneth Perera
- Role, BBC World Service
Bassam Aramin musulumi ilẹ Palestine ati Rami Elhanan Jew lati Israel jijọ padanu ọmọ wọn obinrin ninu ikọlu to n waye bayi laarin orileede mejeeji.
Israel ni wọn jijọ n gbe nibi ti ọpọ yoo ro pe igbe ọta ni wọn yoo maa ba ara wọn gbe lẹyin iṣẹlẹ buruku to waye si wọn.
Kaka ki awọn mejeeji maa foju ọta wo ara wọn,Basam ati Rami sọ ara wọn di ọrẹ ti wọn si n tọ oju ọna idọrẹ ati alaafia.
Ọkunrin ọlọpaa Israeli lo yinbọn pa ọmọ obinrin Bassam Abir,Bassam.Ọmọ ọdun mẹwaa.
Ọmọ ti Rami Smadar padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu lati ọwọ ọmọ ikọ Hamas.Ọmọ ọdun mẹrinla nii ṣe.
Wọn ni ibanujẹ ọkan lo mu ki awọn mejeeji di ọrẹ airoti tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Bassam Aramin / Rami Elhanan
Rami sọ pe "Awa kii ṣe ẹranko a si le lo ọpọlọ wa.A si bẹrẹ si ni beere lọwọ arawa pe njẹ pipa ẹlomii yoo mu ẹmi ọmọ mi pada?''
''Koda ti o ba pa gbogbo awọn ọmọ Jew to ku lorilẹ aye,kii ṣe awọn nikan,titi lae ko le da ọmọ mi pada''
Bẹẹ naa ni Basam sọ.
Ẹgbẹ awọn obi
Lẹyin ti wọn pa awọn ọmọ wọn obinrin,awọn arakunrin yi darapọ mọ ẹgbẹ awọn obi ti wọn pe orukọ ara wọn ni ''The Parents Circle.''
Awọn obi yi jẹ obi to padanu ọmọ wọn ninu ikọlu to n waye.
Bassam loun n foju wo Rami to jẹ ọmọ ogun ilẹ Israel gẹgẹ bi aṣaaju.
Rami ni tiẹ sọ fun BBC nipa Bassam pe :
''O jẹ ẹni to sunmọ mi julọ laye.A ko nilo lati sọrọ ka to gbọ ara wa ye...O jẹ ẹni ti mo n wo lawokọṣe.A maa fun mi lagbara ''
Basaam ti wọn sọ sẹwọn tori e o ju ado oloro lu awọn ọdọ Israeli kan lo wa n tọju Rami bi igba pe ọmọ iya kanna ni wọn.
Bassam sọ fun BBC pe ''ọmọ iya ni wa.Ibaṣepọ wa kọja ti ogun to n lọ lọwọ tori ero wa papọ. Ọrọ ẹdamọniyan jẹ wa logun.A nifẹ si ọrọ ijọba awarawa ati ominira'.'

Oríṣun àwòrán, Rami Elhanan
Ikọlu ti ko lopin
Lati ọjọ Keje oṣu Kẹwaa ni Israel ti n ju ado oloro lu Gaza lẹyin ti Hamas ṣekupa ọmọ Israeli 1,400 ti awọn 239 mii ṣi yi wa ni igbekun wọn.
Ileeṣẹ ilera Hamas sọ pe o le ni ẹgbẹrun mẹewaa ọmọ Palestine to ti ku lati igba ti Israel bẹrẹ si ni gbẹsan ikọlu Hamas pada.
Basaam ati Rami ṣapejuwe ikọlu ọlọdun gbọọrọ to n lọ lọwọ yi gẹgẹ bi eleyi ti ko lopin.

Oríṣun àwòrán, Bassam Aramin
Iku Smadar
Lọjọ Kẹrin osu Keje ọdun 1997 ni Smadar padanu ẹmi rẹ ninu ibugbamu kan lasiko toun ati awọn ọrẹ lọ ra nkan.
''Nise laa n lọ lati ile iwosan kan si ikeji,agọ ọlọpaa kan si ikeji''
Rami sọ pe ''Nigba ti ilẹ ṣu la to pada ba arawa ni ile igbokupamọ si.Nibẹ la ti ri nkan ti ako le gbagbe titi laelae''
''Ibinu to ba iṣẹlẹ yi wa ko ṣe farada.Ohun to si yatọ nipa ọgbẹ ọkan yi ni pe ko fi igba kankan kuro lọkan''
Ado oloro Hamas ati ọta ibọn Israeli
Rami ati Basam kọkọ pade ni ọdun 2005 ni igba akọkọ lasiko apero awọn ọmọ ogun tẹlẹri lati igun mejeeji.

Oríṣun àwòrán, Bassam Aramin
Lọjọ Kẹfaa oṣu Kini ọdun 2007 ni ọmọ Bassam obinrin Abir ọmọ ọdun mẹwaa kagbako iku nigba ti ọta ibọn ti ologun aṣọbode Israeli kan yin ba lori niwaju ile ẹkọ rẹ to wa ni West Bank.
Lẹyin ọjọ mejito lo ni ile iwosan lọlọjọ de.
''Inu n bi mi. Inu ṣi n bi mi titi di oni.Idi si ni pe ẹlẹran ara ni gbogbo wa ko si ni laifi ti iru nkan bayi ba mu inu bi eeyan''
'Gbigbẹsan ko le mu opin ba ọgbẹ ọkan rẹ'
"Amọ o onigbagbọ ni mi mo si mọ pe gbigbẹsan kọ lọna abayọ.Ko le da ọmọ mii pada''
Rami ati iyawo rẹ duro ti Bassam ati mọlẹbi rẹ lasiko inira wọn bi wọn ṣe wa ṣoju ẹgbẹ awọn obi taa mọ si 'The Parents Circle.'

Oríṣun àwòrán, Rami Elhanan
"Nise lo dabi ẹni pe mo padanu ọmọ mi lẹẹkeji ni.''
Bẹẹ ni Rami ṣe sọ.
Lẹyin ọjọ meji Bassam naa darapọ mọ ẹgbẹ awọn obi, The Parents Circle.
Mimu opin ba 'ikọlu ayeraye'
Bassam ati Rami ti wa n jijọ ba awọn eeyan sọrọ lapejọ orisi.
''Bi ko ba si pe eeyan kan gbalẹ onilẹ a ko nilo lati maa pa ara wa.O ti togẹ bayii.Ẹjẹ taa n ta silẹ yi ti pọju''
Bassam sọ bayii ninu ọrọ to fi mẹnuba bi Israel ti ṣe gba ilẹ orileede Palestine lọdun 1948.
Ọrọ yi ko wọpọ lati gbọ lẹnu ọmọ Israel.
O ni ''ohun ti ko yẹ kowaye ni ki awọn kan jẹ gaba lori awọn mii.Ohun ti ko bojumu ni bi Israel ṣe jẹ gaba lori Palestine.A padanu awọn ọmọ wa tori elyi.a ni lati yi nkan pada''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn mejeeji a maa ba awọn ọdọ sọrọ ni paapa awọn to wa ni ile ẹkọ girama ni origun mejeeji.
Gẹgẹ bi Rami ṣe ṣapejuwe rẹ, ''O dabi pe ki eeyan jade sẹnu ilẹ riri to gbona jain jain ni.O ni niṣe ni inu awọn tawọn n ba sọrọ maa n ru''
Esi taa n gbọ lẹnu wọn jẹ ohun to yani lẹnu.
Nigba mi wọn a maa fẹsun kan ara wọn,koda wọn a tun maa ṣepe gaan naa.
''Amọ nigba taa ba fi pari,ko ni si ọdọ kankan ninu wọn ti ko ni maa miri pe odod ọrọ ni ọrọ taa ba wọn sọ.Ohun iyalẹnu ni.A ribi doola agbaye lo ri gẹgẹ bi wọn ṣe kọ wa ninu ẹsin Judaism wa''
Idarijin
Pẹlu ikọlu to n waye latari ikọlu Hamas yi, Rami sọ pe ati ba awọn eeyan sọrọ nipa alaafia yoo lagbara diẹ.
''Igboro ko rẹrin bayii''
O sọ fun BBC pe aimọye iwe atẹjiṣẹ ọrọ inunibini lawọn eeyan ti n fi ranṣẹ si oun.
''Wọn ko le yọ Hamas biigbati eeyan n pa eṣinṣin tabi bi ẹfọnEro ọkan ni Hamas jẹ. Lati le pa ẹfọn run, a ni lati gbọn omi odo adagun to n ye ẹyin si ni.'

Oríṣun àwòrán, Rami Elhanan
Alaafia ọlọjọ pipẹ
Awọn baba mejeeji yi lero lati ri alaafia nigba aye wọn.
''Bassam sọ pe ''Mo pade ẹni to ṣeku pa ọmọ mi niwaju adajọ.Mo sọ fun pe o jẹ ẹni to farakasa ni.Mo sọ fun pe kii ṣe ọta tabi agbesunmọmi lo pa.Ọmọ ọdun mẹwaa ti ko mọwọ mẹsẹ lo pa''
''Ohun naa farakasa ẹkọ ti wọn fun ni.Adisọkan atiitan ti wọn fi tọ dagba''
Ọrọ rẹ kii ṣe fun awọn Israeli ati Palestine nikan bi kii ṣe fun gbogbo awọn to n kopa ninu ikọlu ati ogun lagbaye.
Olootu apilẹkọ Andrew Webb












