“Àwọn akẹgbẹ́ mi 99 tó jẹ́ òṣìṣẹ́ United Nations ló ti bá ogun lọ ní Gaza"

Oríṣun àwòrán, bbc
Adari eto iroyin fun ajọ United Nations lori ọrọ awọn atipo ni Palestine, UNRWA, Juliette Touma, ti sọ pe ojojumọ ni nnkan buru si ni Gaza.
Tourma sọ pe bi awọn eeyan ṣe n ku nibẹ lọpọ awọn mii n di alaabo ara, eyii ko si yọ awọn akẹgbẹ oun silẹ.
Lọwọ yii, UNRWA n ṣeranlọwọ fun nnkan bii 700,000 eeyan to n gbe kaakiri ile awọn ogunlende bii 150 ni Gaza.
Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC, o ni bi awọn araalu ṣe n ku sinu ogun naa to n lọ lọwọ lawọn akẹgbẹ oun, to jẹ oṣiṣẹ UN naa n padanu ẹmi wọn.
Gẹgẹ bii oun to sọ, ko din ni eeyan mọkandinlọgọrun to jẹ oṣiṣẹ UN to ba ogun naa lọ bayii.
O ni “A ko ni ọpọ oun elo ti a nilo, bẹẹ tun ni a n koju iṣoro aisi epo bẹntiro.”
Tourma ṣalaye pe ọpọ awọn ọmọde lagbegbe naa n tọrọ burẹdi ati omi lọwọ awọn oṣiṣẹ UN to n bẹ Gaza wo.
Yatọ so ogun to n waye ni Gaza, obinrin naa sọ pe ọpọ iṣoro lawọn eeyan agbegbe naa n dojukọ, wọn si nilo iranlọwọ ni kankan.
Lati le pese iranlọwọ to yẹ, o ni UNRWA nilo epo bẹntiro, o si nilo ki wọn dawọ ogun duro fun akoo diẹ.
Ko si aye lati gbe epo bẹntiro wọ Gaza lati igba ti ẹgbẹ Hamsa ti kọlu orilẹ-ede Israel lọjọ keje, oṣu Kẹwaa.
Amọ Israel ti sọ pe ọpọ epo lo wa ni Gaza ṣugbọn Hamas lo n ko epo naa pamọ.
Wayi o, ajọ UN ti sọ pe wọn nilo ọpọ epo ni Gaza, bo tilẹ jẹ ijọba Amẹrika ni epo pọ yanturu nibẹ.













