Kí ló dé tí Ìyá ọmọ 'Mummy Calm down' gbà ẹ̀mí ara rẹ́?

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo ni awọn ti mu ọkọ iya ọmọ ‘Mummy Calm Down’ si ahamọ.
Saaju ni iroyin jade pe Arabinrin Toluige Olokoobi Babalola gbe ẹmi ara rẹ niluu Benin.
Ọkan lara olugbe agbegbe naa ti ko fẹ ka darukọ oun ni ohun iyalẹnu ni isẹlẹ naa jẹ fun ọpọlọpọ eeyan.
O ni Babalola ni osisẹ ile iwosan kan, ti ọkọ rẹ si awakọ ti wọn si jọ gbe papọ ni alaafia, ti awọn ko si le sọ boya idile naa n la nkankan kọja.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, oun ni ohun ti awọn gbọ nipe Iya naa gba ẹmi ara rẹ niwaju ọmọ rẹ, ọmọ ọdun kan.
Ki ni Ileeṣẹ ọlọpaa sọ?
Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo, Chidi Nwabuzor fidi isẹlẹ naa mulẹ , to si ọkọ obinrin naa ti wa ni ahamọ.
“Fun ara ọkọ lo gbe ọrọ naa wa si agọ wa. O ni oun de lati ọja ni oun ba iya oun to ti fi okun pa ara rẹ.”
Nwabuzor fikun pe, “O ni bi oun ṣe suure pe awọn ara adugbo pe ki wọn wa, ti wọn tele oun lọ ile iwosan nibi ti wọn fidi rẹ mulẹ pe o ti jade laye.”
O ni lati ile iwosan ni wọn ti gbe lọ ile igbe oku si, ti DPO si bu ẹnu atẹlu bi wọn ṣe kuna lati kọkọ fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.
Tani ‘Mummy Calm Down’?
Lọdun 2020, ni ọmọ obinrin yii di ilumọka lẹyin ti fọnran kan jade lori ayelujara nibi to ti n sọ fun iya rẹ pe ko ni suuru bi o ṣe bawi.
Arabinrin Babalola sọ fun BBC lasiko naa pe fọnrannaa mu ayipade si igbe aye wọn,
“Awọn eeyan ti n ko lero lati ba sọrọ, ni mo n ba sọrọ, ti mo si n pade wọn.”
Ti a ko ba gbagbe, Iya ati ọmọ pade Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, to si lo ọrọ ọmọ naa ninu ọrọ ikini kudun lọdun naa.















