Nítorí pé Bàbá Mohbad gbé obìnrin míì wá sílé wa tí mo sì sọ̀rọ̀ ní wọ́n ṣe n bínú sí mi- Wumi

Oríṣun àwòrán, MOHBAD/INSTAGRAM
Ìyàwó Mohbad sàlàyé ìdí tí Mohbad kò kí ń fi lọ ilé ìwòsàn
Iyawo olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Oladimeji Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad ti salaye idi ti ọkọ rẹ ko ki lọ ile iwosan lasiko to fi ọwọ rẹ ṣeṣe.
Didahun si ibeere ko sẹyin bi awọn eeyan kan ṣe fẹsun kan an pe ko gbe ọkọ rẹ lọ ile iwosan.
Wummi Aloba farahan ni ileẹjọ to n ṣe iwadi lori ohun to sokunfa iku Mohbad to jẹ ọkọ rẹ lọjọ Isẹgun.
O salaye idi ti ọkọ rẹ fi korira lilọ ile iwosan lẹyin gbogbo idunkoko to ti sẹlẹ lasiko to wa ni abẹ ileeṣẹ orin Marlian.
Wunmi ni iṣoro bẹrẹ fun Mohbad kete to n gbero lati kuro labẹ ileeṣẹ orin Marlian, ti awọn ajọ alaabo to gbe ogun ti egbogi oloro, NDLEA si ṣe ikọlu ile ti Ọga isẹlẹ orin naa gbe fun awọn to n sisẹ labẹ rẹ.
Nitori pe Baba Mohbad gbe obinrin kan wa sile wa ti mo si sọrọ ló ṣe pada korira mi- Wumi
Ẹgbọn mi obinrin lo sọ pe ki n ju aṣọ sinu posi ọkọ mi Mohbad nigab ti wọn fẹ sin in pe bo ṣe yẹ ko ri ni yẹn.- Aya Mohbad
Wumi sọ fun ile ẹjọ pe oun ko mọ itumọ aṣọ ti oun sọ sinu posi naa rara.
"Wọn fi ibọn gba Mohbad lori, wọn tun fun nnkan mu"
“O sọ fun mi pe wọn fi nnkan gba ori oun, to si jẹ pe ati igba iyẹn ni ko ti mọ bi o ṣe n ṣe oun,” eyi ni ọrọ ti Wunmi sọ fun Ileẹjọ.
Iyawo, ẹni to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun ni ọrẹ oun ati Mohbad bẹrẹ lati igba ti wọn ti wa ni ile ẹkọ girama ko to di pe wọn ṣe igbeyawo.
O sọ fun ileẹjọ gbogbo idunkoko ti Mohbad lakọja ko to jade laye, paapa bi Ajọ NDLEA ṣe mu Mohbad.
“A gba ipe pe NDLEA lọ si ile orin lati lọ ko awọn eeyan. Ọkọ mi pariwo pe awọn eeyan oun(Zinoleesky ati Adura Aloba) wa lara awọn ti wọn mu, to si eure lọ sibẹ.
“Ile ti NDLEA ṣe ikọlu si jẹ ile Naira Marley gba fun gbogbo awọn olorin to wa labẹ ileeṣẹ olorin Marlian,”
O jẹ ko di mimọ pe ajọ NDLEA fiya jẹ ọkọ bi oṣe bere pe kilode ti wọn fi mu awọn eeyan oun. Isẹlẹ yii waye ninu oṣu keji ọdun 2022.
“Wọn fi sẹkẹsẹkẹ si ọwọ Zinoleesky ti ọkọ mi si n bere lọwọ ẹsọ aabo pe ki ni wọn ṣe sugbọn eyi lo fa lilu. Wọn na ọkọ mi, ti mo si bere pe kilode ti wọn fi na ọkọ mi.
“Wọn fẹ gbe wọn kuro ni ẹsitati ti wọn n gbe sugbọn aṣole ko gba fun wọn eyi lo jẹ ki awọn ajọ NDLEA bẹrẹ si ni ma yinbọn soke. Wọn na mi subu wọ ninu irẹ ti wigi mi fi si danu kuro lori mi, ti wọn si gbe ọkọ mi ati awọn yooku lọ.”
Iyawo oloogbe jẹ ko di mimọ pe wọn tu ọkọ oun silẹ ni alẹ ọjọ naa, to si bẹ wa pe ki a gbe oun lọ ile iwosan nitori wọn fun oun ni nnkan funfun kan mu.
“O sọ fun mi pe wọn fun oun ni nnkan funfun mu, to si jẹ lotitọ mo ri nnkan funfun ni ẹnu rẹ nigba to pada de. Ọkọ mi ni oun nikan ni wọn fun ni nnkan funfun naa mu ki wọn to tu silẹ.
“Mo ri egbo kan ni ori rẹ nigba ti a de ile iwosan, nigba ti mo bi pe kilo mu nibẹ, o ni wọn fi ibọnj gba oun lori.”
Wunmi ni lati igba ti isẹlẹ naa ti waye ni igbagbe ti n ṣe ọkọ oun, ti ko si mọ bi o ṣe n ṣe mọ.
“Lati igba na, ko fi inu tan ile iwosan mọ nitori bi wọn n ṣe dunkoko mọ, Awọn to n dunkoko mọ ni ẹnu ni bi gbogbo, ti wọn si le san owo,”
"Ko si owo ni banki Mohbad nigba to kuro ni Marlian"
Wunmi tẹnu bọ ọrọ nipa irinajo Mohbad pẹlu ileeṣẹ orin Marlian ati ohun to waye laarin oun ati Naira Marley.
O ni o to bi ọdun mẹwaa ti oun ti mọ Mohbad, ti oun si mọ bi o ṣe n tiraka lati jẹ eeyan ko to di pe o tọwọbọ iwe adehun pẹlu Ileeṣẹ orin.
“Nigba ti mo pade rẹ, olorin ni, ti emi naa si jẹ olorin lati ile ẹkọ girama. O kopa ninu idije kan ti BaadyOsha gbe sori ayelujara, to si yege.
“Lọjọ kan o sọ fun mi pe Naira Marley kan si oun lori ayelujara Instagram pe ki awọn pade. Mo gba ni imọran pe ko kọrin pẹlu Naira Marley sugbọn ko ma tọwọbọ iwe adehun pẹlu rẹ sugbọn o ni titọwọ bọ iwe adehun yoo ṣe anfani orin kikọ rẹ.
Wunmi ni oun ko mọ Naira Marley lati ibi kankan ayafi igba ti Mohbad bẹrẹ si ni ma sọrọ rẹ fun oun sugbọn wahala bẹ silẹ nigba wọn ko gba ko parọ olootu rẹ.
“Mohbad fẹ parọ olootu rẹ nitori Tunde to jẹ aburo Naira Marley to n se olootu rẹ ko ṣe nkankan fun sugbọn ọga ni awọn ni yoo olootu tuntun fun un.
“O bẹrẹ si ni gba idunkoko, ti wọn si n pakuro mọ, ara rẹ ko balẹ to fi kuro abẹ wọn lọdun 2022. Ko si owo kankan ninu apo banki rẹ nigba to kuro, ko si owo lati fi bẹrẹ, to si jẹ pe a ti jẹ gan nira.
"Lẹyin Olamide ati Bella Shmurda to duro ti, awọn olorin yooku saa fun Mohbad"
Wunmi sọ fun ileẹjọ pe awọn to n dunkoko mọ Mohbad n lo gbogbo ọna lati dẹruba .
O salaye bi igbesi aye Mohbad ṣe ri lẹyin to kuro Marlian , to si jẹ pe ọpọlọpọ awọn olorin ko fẹ ni ibaṣepọ kankan pẹlu rẹ.
Wunmi ni Mohbad kan si ọpọ olorin sugbọn wọn lati fun lesi .
“O kan si ọpọlọpọ awọn olorin sugbọn wọn ko fẹ ba ni nnkan pọ lẹyin Olamide ati Bella Shmurda, awọn to n dunkoko mó yii setan lati san owo fun ẹnikéni lati fi nkan ṣe ọkọ mi, to si jẹ pe inu ẹru lo wa to fi jade laye.
“Bella Shmurda lo n bọ wa fun bi oṣu mẹta nigba ti wahala yii bẹ silẹ nitori a ko ni nnkan.”
O sọ pe ọkọ oun bi lẹyin si ile igbọnsẹ ti nọọsi fun ni abẹrẹ
O kede ti ọkọ oun gba abẹrẹ lo bẹrẹ si ni ma pariwo, to si lọ bi si ile igbọnsẹ.















