Iléẹjọ́ gba béèlì Emefiele lẹ́yìn ọjọ́ 151 ní àhámọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Adajọ Olukayode Adeniyi ti ileẹjọ giga to n joko niluu Abuja ti gba beeli Gomina fun banki apapọ tẹlẹri, Godwin Emefiele.
Adeniyi palasẹ pe ki Emefiele ma tẹle awọn agbẹjọro rẹ lọ lẹsẹkẹsẹ, ti wọn si ṣe ileri pe awọn yoo mu wa si ileẹjọ ni ọsẹ to n bọ tabi ọjọkijọ ti ileẹjọ ba fẹ ko faran.
Gẹgẹ bii Adajọ ṣe sọ, Gomina Banki apapọ tẹlẹ naa gbọdọ fi gbogbo awọn iwe irina naa rẹ silẹ ni ileẹjọ.
Bakan naa ni Adajọ ni opin gbọdọ de wiwa rẹ ni aham, pẹlu bi o ṣe ti wa ni ahamọ lati bi ọjọ mọkanlelaadọjọ, ti ijọba apapọ ati agbẹjọro agba lorilẹede Naijiria si gbọdọ tẹle asẹ ileẹjọ.
Agbẹjọro ijọba apapọ, Oyin Koleoso tako ipe Emefiele lati gba beeli nitori o ṣe ko tako wiwa si ileẹjọ rẹ lọjọ kẹdogun oṣu kọkanla ni bi to wọn yoo tun fi ẹsun mirana kan .
Farouk Abudalla, agbẹjọro fun Ajọ EFCC ni Emefiele ko ti lo oṣu mẹta ni ahamọ wọn fun idi eyi ki ile ẹjọ ma fun ni beeli.
Sugbọn Adajọ Adeniyi tako ipe EFCC to ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹwaa ni Emefiele de si ahamọ wọn.
Ileẹjọ wa fa Emefiele fun agbẹjọro agba, Matthew Burkaa SAN, ẹni to gbọdọ pese lọjọ ti ijọba apapọ ba fẹ gbe wa si ile ẹjọ.
Ki lo sẹlẹ saaju?
Saaju ni wọn igbẹjọ rọ lori ẹsun iwa ajẹbanu oni biliọnu mẹfa ati ẹẹdẹgbẹrun miliọnu Naira (N6.9 billion) ti ijọba apapọ fi n kan gomina agba tẹlẹ fun Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele niwaju ile ẹjọ giga apapọ nilu Abuja.
Emefiele ti wa ni ahamọ awọn agbofinro DSS lati igba ti aarẹ Naijiria, Bọla Tinubu ti paṣẹ ko lọ rọọkun nile ni ọjọ kẹsan oṣu kẹfa ọdun 2023.
Ẹsun ti wọn n fi kan an ni pe o lo ipo rẹ lati fun Yaro to jẹ oludari ni ileeṣẹ naa lawọn anfani ti ko tọna labẹ ofin.
Iwe ẹsun ti ileeṣẹ eto idajọ gbe ka iwaju ile ẹjọ naa sọ pe, ọkọ ayọkẹlẹ mejidinlọgọrun atawọn ọkọ ayẹta ti owo rẹ to biliọnu mẹfa ati ẹẹdẹgbẹrun miliọnu Naira (N6.9 billion).















