Wo bí ìyanṣẹ́lódì àwọn òṣìṣẹ́ ṣe lọ láwọn ìpínlẹ̀ jákèjádò Nàìjíríà

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti

Yoo waye ko ni waye lawọn ọmọ Naijiria fi jo lowurọ ọjọ Iṣẹgun ti agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria NLC ati TUC kede pe awọn yoo gun le iyanṣẹlodi.

Awọn akọroyin BBC Yoruba to fọn kaakiri awọn ipinlẹ Naijiria jabọ lorisi to ṣafihan bi awọn ipinlẹ kọọkan ti ṣe mu ọrọ iyanṣẹlodi yi si.

Baa ṣe ṣalabapade awọn to tẹle aṣẹ NLC ati NUC latina tan bi owo nidi iyanṣẹlodi yi, bẹẹ naa la tun ri awọn ipinlẹ ibomiran to ṣe pe igbiyanju diẹ lo wayenlori iyanṣẹlodi yi.

Atupalẹ bi iyanṣẹlodi naa ṣe lọ ree lawọn ipinlẹ taa fi akọroyin wa ranṣẹ lati mọ bi nkan ṣe lọ

Ipinlẹ Ogun: Awomọju lẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ n'ipinlẹ Ogun n wo iṣẹ

Paroparo ni ileeṣẹ oṣiṣẹ da ni ipinlẹ Ogun

Gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ patapata n'ipinlẹ Ogun ni wọn n pada sile wọn nigba ti wọn rii pe lotitọ ni iyanṣẹlodi alainigbedeke ti bẹrẹ.

Ṣaaju asiko yii ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ Nigeria Labour Congress, NLC ati Trade Union Congress, TUC ti kede pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi alainigbedeke.

Nigba ti BBC Yoruba n lọ kaakiri igboro ilu Abẹokuta lati mọ bi awọn oṣiṣẹ ṣe mu ọrọ iyanṣẹlodi naa lọkunkundun, pupọ awọn oṣiṣẹ ni wọn joko sile wọn.

Diẹ lara awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ to wa lagbegbe Oke-Mọsan niluu Abẹokuta ti wọn lọ si ibi iṣẹ lonii sọ pe awọn kan lọ lati mọ ohun to n ṣẹlẹ ni.

Awọn oṣiṣẹ naa ti wọn sọ pe ka fi orukọ bo awọn laṣiri ni awọn kan lọ lati mọ boya iyanṣẹlodi naa yoo fi ẹsẹ mulẹ.

Ninu ọrọ wọn, "Igba ti a de bi la ṣe akiyesi pe iyanṣẹlodi yii waye lootọ, nitori pe a ko ro pe yoo fi ẹsẹ mulẹ.

Aworan ileeṣẹ ilẹ ati ọrọ ile ijọba apapọ to wa ni Oke Mosan Abeokuta

Abuja: Iṣẹ ko dawọ duro ni olu ilu Naijiria

Aworan ileeṣẹ ijọba apapọ niluu Abuja

Ko si adinku kankan to ba lilọ bibọ ọkọ ni Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria lọjọ to yẹ ki iyanṣẹlodi ti ẹgbẹ oṣiṣẹ pe fun ko waye.

Ati ileeṣẹ ijọba ati aladani, o jọ pe gbogbo wọn kọ lati tẹle aṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ.

Akọroyin wa jabọ pe awọn ile ifowopamọ naa ko s agadagodo si ọfisi wọn ti gbogbo lilọ bibọ ko si dawọ duro rara ati rara.

Nipinlẹ Osun awọn oṣiṣẹ ati ile ifowopamọ keti ikun si ikede NLC lati yanṣẹlodi

Ileeṣẹ oṣiṣẹ ipinlẹ Osun

Akọroyin wa fẹsẹ kan de ileeṣẹ ijọba to wa ni Abeere ni ipinlẹ Osun to si jabọ pe awọn oṣiṣẹ n ba iṣẹ wọn lọ lai si idaduro kankan.

Yatọ si awọn oṣiṣẹ ijọba yi, awọn ọlọja ati awakọ ero naa ko da iṣẹ duro rara.

Bẹẹ naa si ni awọn ile ifowopamọ naa n da alabara wọn lohun lai si idiwọ kankan.

Amọ ile ẹjọ giga to kalẹ siluu Oshogo da paroparo ti ko si si awọn oṣiṣẹ kankan to yọju si ibiṣẹ ninu wọn.

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun to wa niluu Oshogbo

Ondo: Ọpọ awọn ọfisi lowa ni ṣiṣi n'ipinle Ondo

Aworan ọfisi oṣiṣẹ nipinlẹ Ondo

Awọn oṣiṣẹ kan pada lọlẹ lẹyin ti wọn ti ṣaaju wa si ẹnu iṣẹ n'ipinle Ondo toun ti bi abawọle sinu ọgba ileeṣẹ wọn ṣe wa ni titi pa.

Awon oṣiṣẹ ẹka idajo Ondo ko lanfani lati ṣiṣẹ ṣugbọn awon oṣiṣẹ ẹka ijọba miran ni wọn wa si ọfisi.

BBC Yoruba ri pe ileeṣẹ ijọba apapọ to wa ni Akure wa ni ṣiṣi ti awọn oṣiṣẹ kan si wa nikalẹ

Oṣiṣẹ NAFDAC kan ti ko fẹ darukọ rẹ sọ pe awọn ko ti gba aṣẹ kankan lati wa si ọfisi ṣugbọn awọn kan to wa si ọfisi pada lọ si ile

Nile ẹkọ fasiti ijọba apapọ imọ ẹrọ FUTA to wa ni Akure, alaga awọn ẹgbẹ olukọ ASUU Ọjọgbọn Pius Mogaji sọ pe iyanṣẹlodi ti bẹrẹ niibamu pẹlu aṣẹ to wa lati ọdọ aarẹ ASUU Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke l'AWORAN AWbuja.

ASUU darapọ̀ mọ́ ìyanṣẹ́lódì NLC, ìjọba àpapọ̀ ní ìgbésẹ̀ náà lòdì sófin
NLC

Oríṣun àwòrán, @NLCHeadquarters/X

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọsiṣẹ ni Naijiria, NLC ati TUC ti ke si awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ kaakiri Najiria pe ki wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi lati aago mejila oru oni.

Ṣaaju ni ile ẹjọ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ, NIC, ti kọkọ paṣẹ pe ẹgbẹ ọhun ko gbọdọ da iṣẹ silẹ lẹyin rogbodiyan to waye pẹlu adari ẹgbẹ naa nipinlẹ Imo.

Amọ ninu atẹjade kan lọjọ Aje ni ẹgbẹ naa ti ke si awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati bẹrẹ iyanṣẹlodi.

Atẹjade naa ni “Gẹgẹ bii alakalẹ awọn alasẹ ẹgbẹ NLC ati TUC, gbogbo oṣiṣẹ ni Naijiria gbọdọ da iṣẹ silẹ bẹrẹ lati aago mejila oru oni ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun 2023.”

“Fun idi eyii, gbogbo adari ẹgbẹ kaakiri awọn ipinlẹ gbọdọ pin aṣẹ yii fun awọn eeyan wọnw lawọn ọọfisi wọn ati lori ikanni WhatsApp.”

Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko ni fi ohunkohun pamọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ nipa iyanṣẹlodi ọhun, NLC ati TUC sọ pe iha awọn oṣiṣẹ atawọn ọmọ Naijiria ni oun wa.

Eredi iyanṣẹlodi yii

NLC

Oríṣun àwòrán, @NLCHeadquarters

Iyanṣelodi yii wa lara ọna lati pe fun ijiya to tọ fun awọn eeyan kan to lu Aarẹ ẹgbẹ naa, Joe Ajaero, nipinlẹ Imo lọsẹ to kọja.

Ohun to gbe Ajaero atawọn ọmọ ẹgbẹ mii lọ si Imo ko ṣẹyin iwọde lodi si bi ijọba ṣe jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun lowo oṣu mọkanlelọgbọn.

Amọ ṣe lawọn eeyan kan da seria fun olori ẹgbẹ naa, ti wọn si lu u ni ilu bara.

Ikọlu na ti mu ki ẹgbẹ ọhun fẹsun kan ijọba ipinlẹ ọhun pe oun lo mọọmọ ran awọn janduku si oun.

Bakan naa ni wọn ni ki ijọba pe awọn ẹgbẹrun mẹwaa oṣiṣẹ ti wọn pe ni ayederu pada sẹnu iṣẹ ni ipinlẹ Imo.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Àwa náà má darapọ̀ mọ́ ìyanṣẹ́lódì NLC

Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìyẹn Academic Staff Union of Universities (ASUU) ti darí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn láti darapọ̀ mọ́ ìyanṣẹ́lódì tí NLC gùnlé.

Ààrẹ ASUU, Emmanuel Osodoke nínú ìwé àkọránṣẹ́ kan tó kọ sí gbogbo àwọn alága ASUU ní gbogbo ẹ̀ka wọn ní kí wọn darí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn láti darapọ̀ mọ́ ìyanṣẹ́lódì náà.

Osodeke ní bí àwọn ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka NLC, ó pọn dandan fún àwọn láti kópa nínú ìyanṣẹ́lódì náà.

Ó ní ìgbésẹ̀ NLC láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì náà jẹ́ láti dá à[bò àwọn òṣìṣẹ́ tí gbogbo òṣìṣẹ́ sì gbọdọ̀ kún wọn.

Bákan náà ló rọ ìjọba àpapọ̀ láti san gbèsè owó oṣù wọn mẹ́rin tó kù nínú oṣù mẹ́jọ tí ìjọba tó kọjá kò san fún wọn lásìkò tí ASUU lọ fún ìyànṣẹ́lódì lọ́dún 2022.

Àtẹ̀jáde ASUU

Oríṣun àwòrán, @NLCHeadquarters/X

Yàtọ̀ sí ASUU, àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ mìíràn náà ti kéde pé àwọn máa darapọ̀ mọ́ NLC láti yan iṣẹ́ lódì.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Ìgbésẹ̀ NLC láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì nítorí Ajaero lòdì sí òfin - Ìjọba àpapọ̀

Ìjọba àpapọ̀ ti ní ìgbésẹ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì aláìní gbèdéke jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ ti dá wọn lẹ́kun láti má ṣe bẹ́ẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan tí olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ìròyìn àti ọgbọ́n inú, Bayo Onanuga ní bí NLC àti TUC ṣe darí àwọn òṣìṣẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lọ́jọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kọkànlá ọdún 2023 lòdì sí ìdájọ́ tí Adájọ́ Benedict Backwash Kanyip gbé kalẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Ìjọba àpapọ̀ ní ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn pé àwọn adarí NLC àti TUC fẹ́ kó bọwọ́bọwọ́ sí ìjọba lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ tí kò ìjọba rárá.

Wọ́n ní kò yé àwọn ìdí tí NLC àti TUC ṣe fẹ́ fìyà jẹ gbogbo àwọn ènìyàn Nàìjíríà látàrí ìfaǹfà tó wáyé láàárín ààrẹ NLC, Joe Ajaero àtàwọn agbófinró ní ìlú Owerri, ìpínlẹ̀ Imo lórí ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n fẹ́ ṣe.

Onanuga nínú àtẹ̀jáde náà fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba àpapọ̀ kò fara mọ́ ìfìyàjẹni ní àwọn ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ti pàṣẹ pé kí ìwádìí tó gbòòrò ó wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá tó wà níbẹ̀ lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà fi wáyé ni wọ́n ti gbé kúrò níbẹ̀ lọ sí ìpínlẹ̀ mìíràn.

Ó ní pípè fún ìyanṣẹ́lódì gbogbo òṣìṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ́ ti ara ẹni jẹ́ àṣìlò agbára àti pé ó yẹ kó máa lo ipò rẹ̀ láti mú àgbéga bá ọ̀rọ̀ orílẹ̀ èdè ni.

Bákan náà ló fi kun pé kò yẹ kí àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ máa lọ́wọ́ nínú títàpá sí àṣẹ ilé ẹjọ́.

Ó ní ohun ti àwọn mọ́ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ mọ́ látilẹ̀ ni bíbọ̀wọ̀ fún òfin àmọ́ tí àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tó wà níbẹ̀ lásìkò kò nání òfin.

ÌjọbA àpapọ̀ tẹmpẹlẹ mọ pé ìyanṣẹ́lódì náà kò bá òfin mu àti pé wọ́n kàn mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ fi mú ìnira bá ará ìlú ni.