Àjọ WHO kọminú lórí bí kò ṣe sí ilé ìwòsàn tó ń ṣiṣẹ́ ní Gaza mọ́

Ìta ilé ìwòsàn Al-Shifa

Oríṣun àwòrán, AFP

Àjọ ètò ìlera àgbáyé WHO ti ní kò sí ilé ìwòsàn kan tó ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ ní Gaza mọ́.

Ọ̀gá àgbà WHO, Tedros Adhanom Ghebreyesus ní lemọ́lemọ́ ni àdó olóró ń dún ni agbègbè ilé ìwòsàn Al-Shifa tó wà ní Gaza.

Adarí ẹ̀ka iṣẹ́ abẹ ní ilé ìwòsàn Al-Shifa, Dókítà Marwan Abu Saada ní àwọn ọmọ ọwọ́ mẹ́ta tí wọ́n bí nígbà tí oṣù wọn kò ì tíì pé ni wọ́n ti pàdánù ẹ̀mí látàrí pé kò sí ohun èlò láti fi tọ́jú wọn.

Dókítà Marwan ní àìsí iná láti fi fún àwọn náà ní ìtọ́jú tó péye ń ṣàkóbá fún pípèsè ètò ìlera tó yarantí.

Ó ní ó ṣeéṣe kí àwọn ọmọ mẹ́rìndínlógójì tó kù tó nílò ètò ìtọ́jú tó lágbára pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí àìlè pèsè ìtọ́jú tí wọ́n nílò fún wọn.

Ó ní inú yàrá tí wọ́n ti ń tọjú àwọn aláìsàn ọkàn ni àwọn kó àwọn ọmọ ọ̀hún sí níbi tí àwọn ti fi aṣọ bò wọ́n lára láìsí ìtọ́jú tó péye fún wọn.

Nígbà tó ń bá BBC sọ̀rọ̀, olórí ẹ̀ka iṣẹ́ abẹ ní àwọn nílò epo bẹntiróòlù láti fi tọná sí ẹ̀rọ amúnáwá tí wọ́n fi máa gbé àwọn ọmọ náà sínú ìgò àti láti pèsè èémí tí àwọn ọmọ náà nílò fún wọn.

Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN ní àwọn nọ́ọ̀sì mẹ́ta ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù tó wáyé ní àwọn agbègbè ilé ìwòsàn náà.

UN ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé àtàwọn ohun èlò ní ilé ìwòsàn náà ni àdó olóró ti bàjẹ́ tán tó fi mọ́ àwọn àmù tí wọ́n ń pọn omi sí àti kàǹga.

Israel ti saájú fẹ̀sùn kàn pé Hamas ń ṣiṣẹ́ ní abẹ́lẹ̀ ilé ìwòsàn tó tóbi jùlọ ní Gaza àmọ́ Hamas jìyàn ẹ̀sùn náà.

Dókítà Marwan Abu Saada ní irọ́ ńlá ni pé ikọ̀ Hamas ń ṣiṣẹ́ nínú ilé ìwòsàn náà àti pé àwọn aláìsàn àtàwọn tó ń ṣe àt]ipó lọ wà nílé ìwòsàn náà.

Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, gbogbo àwọn ibi tó yí ilé ìwòsàn Al-Shifa tó wà ní ẹkùn àríwá Gaza ni àwọn ọmọ Israel ń ju àdọ olóró sí tí àwọn kan sì ní Israel ń mọ̀ọ́mọ̀ ju àdó olóró sí ilé ìwòsàn náà ni.

Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Israel ní àwọn kò ṣe ìkọlù sí ilé ìwòsàn náà pé agbègbè rẹ̀ ni àwọn ń jù ú sí.

Israel gbé ìgbésẹ̀ láti ran ilé ìwòsàn Al-Shifa lọ́wọ́

Àwọn ibi tí àdó olóró bàjẹ́

Oríṣun àwòrán, Reuters

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iléeṣẹ́ ológun Israel bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì kéde láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ènìyàn tó wà nínú ilé ìwòsàn Al-Shifa.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun Israel, Daniel Hagari ní Israel ti ṣí àwọn ọ̀nà kan kalẹ̀ láti àríwá Gaza lọ sí gúúsù Gaza láti fi kó àwọn aláìsàn àtàwọn tó farapa tó wà ní àwọn ilé ìwòsàn náà kúrò.

Daniel Hagari ní àwọn ti ṣetán láti láti ri pé àwọn ọmọ tó wà nílé ìwòsàn tó nílò ìtọ́jú ni wọ́n kó lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn.

Bákan náà lọ fẹ̀sùn kàn pé àwọn ti pèsè epo bẹntiróòlù ọ̀ọ́dúnrún lítà fún ilé ìwòsàn Al-Shifa àmọ́ ikọ̀ Hamas kò jẹ́ kí ilé ìwòsàn ọ̀hún rí epo náà gbé.

Ṣùgbọ́n Hamas gbé àtẹ̀jáde kan síta pé àwọn kò ní kí ilé ìwòsàn má gba epo lọ́wọ́ Israel.

Dr Marwan ní epo ọ̀ọ́dúnrún lítà kò lè kọjá ọgbọ̀n ìṣẹ́jú láti fi tan iná sí àwọn ẹ̀rọ amúnáwá àwọn.

Ilé ìwòsàn náà ní kò dín ní ẹgbẹ̀rún méjì ènìyàn ló wà ní ọ̀dọ́ àwọn tí àwọn ń ṣe àmójútó wọn báyìí.

Wọ́n ní àìsí iná, omi àti oúnjẹ ń fi ẹ̀mí àwọn ènìyàn sínú ewu.

Ajọ tó ń ṣe ìrànwọ́ fún Palestine ní yóò ṣòro láti kó àwọn ọmọ náà kúrò ní Gaza nítorí ìgbésẹ̀ tí wọ́n nílò láti fi kó àwọn náà kò kéré rárá.

Adarí àjọ náà ní pẹ̀lú bí àwọn ọkọ̀ tó le gbé àwọn ọmọ náà kò le dé inú ibi tí àwọn ọmọ náà wà, yóò ṣòro láti lè rí wọn gbé jáde lọ gba ìtọ́jú.

Ó ní ohun tí Israel lè ṣe láti ràn wan lọ́wọ́ ni láti ṣe ìdádúró ìkọlù tí wọ́n ń ṣe sí agbègbè ilé ìwòsàn náà kí epo bẹntiróòlù lè wọ ibẹ̀ láti fi tan iná.

Àjọ ètò ìlera, WHO ti ń pè fún ṣíṣe ìdádúró ìkọlù tó ń wáyé ní Gaza láti dá ààbò bo ẹ̀mí àwọn ènìyàn àti láti pèsè ìlera tó péye.