Wọ́n fi ọwọ́ òsì júwe ilé f’ọ́mọ-ogun méjì Uganda torí wọ́n fẹsẹ̀ fẹ l’ásìkò ìkọlù

Aworan awọn ọmọ ilẹ Afrika ni Solaia

Oríṣun àwòrán, AFP

Ile-ẹjọ ologun lorilẹ-ede Uganda lo ti ni ọmọ-ogun ilẹ naa meji jẹbi iwa ojo l’akoko tawọn agbebọn ẹgbẹ Al-Shabab ṣe ikọlu si agbarijọpọ awọn ọmọ-ogun ilẹ Afirika ni Somalia l’oṣu karun-un ọdun 2023 yii.

Zadock Abor ati John Oluka ni wọn fẹsẹ fẹ nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ Al-Shabab kọlu ibudo ologun Bulo Marer l’apa guusu Mogadishu to jẹ olu-ilu orilẹ-ede Somalia.

Uganda lo darapọ mọ agbarijọ awọn ọmọ-ogun kaakiri ilẹ Afirika ti wọn pejọ lati ba Somalia ṣẹgun ẹgbẹ agbesunmọnmi Al-Shabab.

O kere tan aadọta ọmọ ogun lo padanu ẹmi wọn nibi ikọlu naa to jẹ eyi ti o le ju lọ lati igba ti awọn ọmọ-ogun Atmis ti bẹrẹ sii gbena woju ẹgbẹ Al-Shabab lati ọdun to kọja.

Aarẹ orilẹ-ede Uganda, Yoeri Museveni, ti b’ẹnu atẹ lu iwa awọn ọmọ-ogun ilẹ naa fun iwa abuku ti wọn hu.

Ile-ẹjọ ologun lorilẹ-ede Uganda to fi Mogadishu ṣe ibujoko lo gbọ pe ikọlu naa yoo waye ti wọn si ṣe ikilọ fawọn ọmọ-ogun naa amọ ti wọn kuna lati dena rẹ.

Kaka ki wọn ko awọn ọmọlẹyin wọn mọra lati dana ogun fun awọn agbebọn naa ya, niṣe ni Zadock ati John f’ẹsẹ fẹẹ.

Awọn mejeeji to na papa bora naa ni ajọ ologun ilẹ Uganda ti yọ bi ẹni yọ jiga, ti awọn ọmọ-ogun mẹrin ti ko tii gba iyọnda lati maa gbe’bọn si tun jẹbi ikunna lati daabobo awọn ohun ija ogun to wa nibẹ.

Ẹgbẹrun mọkandinlogun ni oye ọmọ-ogun ilẹ Africati ajọ iṣọkan ilẹ Africa ran lọ Somalia ni 2007 lati le bawọn le ẹgbẹgun Al-Shabab jade lorilẹ-ede naa.

Igbagbọ wa pe awọn ọmọ-ogun naa yoo kuro ni Somalia lẹyin ti wọn ba gbe ijọba lẹ fawọn ikọ ogun ijọba l’ọdun to n bọ.