Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò e-CRVS tí ìjọba àpapọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kéde rẹ̀ àti ànfàní rẹ̀ fún ọ

Oríṣun àwòrán, NATIONAL POPULATION COMMISSION
Ajọ to n ri si eto ikaniyan ni Naijiria, NPC, ti ṣe ifilọlẹ eto electronic Civil Registration and Vital Statistics System (e-CRVS) laarin ọsẹ yii.
Ifilọlẹ yii lo n waye ni ifọwọsowọpọ pẹlu ajọ UNICEF ati ileeṣẹ Barnksforte technologies limited.
Lọjọ ifilọlẹ kan naa yii ni wọn ṣe ifilọlẹ ‘National Geospatial Data Repository’ to gi mọ igbimọ ti yoo maa bojutoeto CRVS.
Nianu atẹjade kan ti ajọ NPC fi lede, o ni awọti eto n ẹrọ naa yoo jẹ ko rọrun lati ṣe iforukọsile awọn araalu atawọn nnkan mii lai fi akoko ṣofo.
Ki wa ni e-CVRS yii, ati pe anfani wo ni yoo ṣe fun awọn ọmọ Naijiria?
Ki ni eto iforukọsilẹ araalu?
O ṣe pataki lati mọ nipa eto iforukọsilẹ araalu ṣaaju ki a to maa sọrọ nipa eto CVRS.
Gẹgẹ bii ohun ti ajọ iṣọkan agbaye, United Nations sọ, o jẹ iforukọsilẹ araalu to pọn dandan, ti yoo maa waye loorekoore, ti yoo si wa ni akọsilẹ.
UN ni iforukọsilẹ naa gbọdọ maa waye ni ilana ofin orilẹ-ede to ba ti n waye.
Awọn ohun pataki to n waye ninu aye onikaluku ni ijọba n gba silẹ, bii akọsilẹ nipa ibi, iku, igbeyawo, ituka igbeyawo, atawọn nnkan mii.
Awọn alaye naa ṣe pataki nitori o jẹ nipa igbesiaye onikaluku lati igba ti wọn ti bi irufẹ ẹni bẹẹ titi ti yoo fi jade laye.
Ni Naijiria, ofin kan an nipa fun araalu lati fi awọn alaye yii silẹ fun ijọba.
Anfani e-CRVS

Oríṣun àwòrán, e-CRVS Screenshot
Gẹgẹ bii ohun ti NPC sọ, ipa mẹta ni anfani e-CRVS pin si; lara rẹ ni ti eto ilera, eto iṣiro, ati ato ilu.
Anfani e-CRVS ipa eto iṣiro
Lara awọn anfani ti eto yii yoo ṣe nipa eto ilera ni iroyin nipa iku ati bi awọn eeyan ṣe n bimọ si.
Iroyin nipa iye ọmọ ti wọn bi lorilẹ-ede yoo sọ iyatọ to wa laarin iye ọmọkunrin ati ọmọbinrin ti awọn araalu bi.
Awọn iroyin yii ni yoo ran ijọba lọwọ lati murasilẹ fun ọjọ iwaju.
Yoo tun jẹ ki ijọba mọ nipa awọn akoko ti awọn eeyan n bimọ julọ ni ninu ilu.
Anfanni e-CRVS fun eto ilera
Awọn imọ nipa iku ati ohun to ṣokunfa rẹ le ran ijọba lọwọ lati pese eto ilera to peye lawọn agbagbe kan to ku diẹ kaato fun.
Fun apẹrẹ, alaye nipa ohun to ṣokunfa iku le ṣe apẹrẹ awọn agbegbe ti iku ti pọ ju ati irufẹ ọjọ ori awọn ti iku n dojukọ.
Anfanni e-CRVS fun abojuto ilu
Akọsilẹ nipa ọjọ ori awọn eeyan, ibi ti wọnw ti wa, awọn wwọn obi ati ẹya ti wọn jẹ wulo pupọ fun ato ilu.
Fun apẹrẹ, iwe ẹri ọjọ ori eeyan le sọ boya irufẹ ẹni bẹẹ le ṣe awọn iṣẹ kan tabi omiran.
Iwe ẹri ọjọ ori tun wulo fun gbigba awọn iwe mii bii iwe irinna ilẹ okere, iwe ọkọ wiwa, atawọn anfani mii fun araalu.












