Àwọn aláṣẹ Fáṣitì yọ alákóso àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípò

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Fasiti ilu Eko ti yọ alakoso awọn akẹkọọ, Ọjọgbọn Tajudeen Olumoko nipo rẹ gẹgẹ bi alakoso awọn akẹkọọ lori ẹsun pe to n pese ayederu iwe ẹri fun awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa.

Saaju ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko kede pe awọn yoo gbe igbimọ kalẹ lati ṣe iwadi ẹsun pe awọn olukọ n gba owo lati fun awọn akẹkọọ ni maaki ati lati gba iwe ẹri

Awọn alasẹ ti wa yan adele , iyẹn Dokita Abiodun Fatai -Abatan gẹgẹ bi alakoso awọn akẹkọọ.

Iroyin jade pe Fasiti LASU pese anfani lati gba iwe ẹri fun awọn akẹkọọ to ba le san milọnu meji si mẹrin lo da le lori iwe ẹri ẹkọ ti wọn ba fẹ.

Nigba to n sọrọ, ọkan lara ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Eko, Amofin Sa’ad Olumoh da laba pe ki ile pe ẹka ICT ileẹkọ lati wa wi tẹnu wọn iwaju igbimọ ti ile igbimọ dasilẹ.

“A ko gbọdọ wa idi awọn alasẹ nikan, awọn fi iwe ẹri sita naa gbọdọ ri ijiya ofin.”