Dókítà Ariyo kan Gift ní ẹ̀ṣẹ́ ní kíláàsì ní OAU, làwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì náà bá n béèrè ìfìyàjẹ Olùkọ́ ọ̀hún

OAU Gate

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo nilu Ile-ife nipinlẹ Osun ni wọn ti rọ awọn adari ile-ẹkọ naa fi iya to tọ jẹ olukọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọmọwe K.F. Ariyo latari bo ṣe fi iya aitọ jẹ akẹkọọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Gift.

Ninu fanran kan to n tan kalẹ lori ẹrọ ayelujara ni a ti rii ti akẹkọọ naa n du ara rẹ lọwọ ọkunrin kan ti wọn pe ni ẹṣọ alaabo.

Nibi ti Gift ti n gbiyanju lati pe lori ẹrọ ilewọ rẹ ni olukọ naa ti n wi fun un pe “ma pe ẹnikẹni. Pa foonu rẹ. Iwọ ko le ju emi lọ, boo tilẹ jẹ, ọmọ giiwa ile-ẹkọ yii, n ko nii gba eleyi fun ọ. Pa foonu yẹn”, ti akẹkọọ naa si n beere pe ki ni oun ṣe.

Akọwe apapọ fun awọn akẹkọọ nile-ẹkọ naa, Opeyemi Akinboni, ṣe alaye fun BBC News Yoruba pe niṣe akẹkọọ naa ṣeesi wọ kilaasi ti Dokita Ariyo ti n kọ awọn akẹkọọ miran to si fẹẹ jade pada ki olukọ ọun o too pee pada.

Opeyemi wi pe Gift ṣe alaye fun Ariyo pe kilaasi oun loun n wa ko too dii pe oun ṣeeṣi wọ kilaasi naa amọ ọrọ naa ko ta leti olukọ ọun.

Ariyo ni won wi pe o pe awọn ẹṣọ alaabo ọgba naa lati waa mu Gift lọ si agọ wọn.

Nibi ifanfa ati ariyanjiyan to waye lẹyin eyi ni olukọ naa ti fẹẹ fi agidi gba ẹrọ ilewọ akẹkọọ naa to sii gbaa jabọ ko too di pe okan akekọọ naa ni ẹṣẹ lẹyin ọrun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ohun táa fẹ́ gan nì yí

Akọwẹ awọn akẹkọọ naa tẹsiwaju pe kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa lawọn ti sọ ẹdun ọkan awọn fun awọn adari ile-ẹkọ ọun lati lee dena laasigbo latọwọ awọn akẹkọọ.

Akọkọ ohun ti wọn beere fun ni ki olukọ naa o tọtọ aforiji lọwọ Gift ati gbogbo akẹkọọ fasiti naa.

Ohun ikeji ni ki awọn adari fasiti naa o ṣe idajọ ododo ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin ile-ẹkọ naa lori ẹni to ba yọ ọwọ ija nibẹ ki wọn ma si fi ọrọ naa ṣe bonkẹlẹ.

Bakan naa ni wọn fẹ idaniloju pe ko nii si ifiyajẹni kankan, yala ni ikọkọ tabi ni gbangba, fun awọn akẹkọọ to wa ni kilaasi nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹ.

Opeyemi waa rọ awọn akẹkọọ lati gba alaafia laaye ki awọn adari fasiti naa o lee roju raye ṣe ohun to tọ.

Bẹẹ naa lo fi da wọn loju pe awọn aṣoju akẹkọọ ko nii gba ki ẹnikẹni o bo ọrọ naa mọlẹ.