Babaláwo, èèyàn márùn-ún míì tí wọ́n lu Timothy Owoeye ní jìbìtì N38M rí ẹ̀wọ̀n he

Oríṣun àwòrán, Facebook/Timothy Owoeye
Ile-ẹjọ giga to n joko niluu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ ẹwọn ọdun marun-un fun babalawo kan, Kazeem Agbabiaka atawọn mẹfa mii.
Eyi waye fun ẹsun pe wọn fi fidio ihooho aṣofin ana nipinlẹ Ọṣun, Timothy Owoẹyẹ sori ayelujara lẹyin ti wọn lu u ni jibiti miliọnu mejidinlogoji naira (38m).
Fẹmi Oyebode, Abdul-Rasheed Ọjọnla, Babatunde Oluajo, Adebiyi Kẹhinde, Oyebanji Oyeniyi ati Ismaila Azeez lo gbimọ pọ lati lu Timothy Owoeye ni jibiti.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun 2018 ni fidio ihooho Owoẹyẹ gba ori ayelujara kaakiri, nibi ti aṣofin Ọṣun tẹlẹ naa ti wa nihooho to si n wẹ laarin ọja.
Ohun tawọn eeyan n sọ nigba naa ni pe etutu ti yoo re iku lori rẹ ni Owoẹyẹ tori ẹ wẹ nihooho laarin ọja, to fi di pe awọn eeyan agbegbe Ọṣunjẹla si n beere ohun ti aṣofin tẹlẹ naa n danwo.
Awọn olujẹjọ ti kootu ran lẹwọn yii mọ nipa fidio to jade naa gẹgẹ bi ẹsun ti wọn fi kan wọn, ati pe lẹyin ti wọn ni ki Owoẹyẹ lọọ wẹ nihooho ti wọn si ti gbowo nla lọwọ rẹ fun iṣẹ iwẹ oru naa ni wọn tun ju fidio naa sita.
Ile-ẹjọ Majistreeti nigbẹjọ naa ti bẹrẹ lati 2018, ki wọn too taari rẹ si ile-ẹjọ giga lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, 2018.
Lẹyin awọn ẹri mẹtadinlọgọta to foju han, ati awọn ẹlẹrii mẹfa to tako awọn olujẹjọ mẹfa yii, Adajọ Emmanuel Ayoola, nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ keje, oṣu kọkanla, ọdun 2023 yii, ran awọn eeyan naa lẹwọn lori ẹsun igbimọpọ ṣiṣẹ ibi, jibiti ori ayelujara to lagbara ati fifi ayelujara dunkooko mọ aṣofin Ọṣun tẹlẹ naa.
Nigba to n sọrọ lẹyin idajọ, Owoẹyẹ dupẹ lọwọ awọn mọlẹbi rẹ, awọn alajọṣe rẹ ninu oṣelu ati ile-ẹjọ to gbe idajọ ododo kalẹ.















