Waec yóò bẹ̀rẹ̀ lílo kọ̀mpútà CBT fún ìdànwò àṣekágbá girama

Oríṣun àwòrán, rivers state ministry of education
Ajọ to n ṣeto idanwo aṣekagba girama lẹkun iwọ oorun Afirika, WAEC ti kede pe awọn yoo bẹrẹ si nii lo ẹrọ ayarabiaṣa kọmputa CBT fi ṣe idanwo aṣekagba naa bayii.
Waec kede lọjọ Aje pe gbogbo ọrọ a n lo beba ati ohun elo iwe gbogbo yoo di afisẹyin ti egungun n fi aṣọ bayii.
Ṣaaju asiko yii ni ajọ to n ṣe idanwo aṣewọle si ile ẹkọ giga fasiti, JAMB ti gbe igbesẹ lati maa ṣe idanwo wọn pẹlu Kọmputa.
Ohun ti a mọ ni pe awọn akẹkọọ agbele ṣedanwo (Private Candidates) ni yoo kkọ janfani eto naa.
Nigba wo ni eto idanwo CBT yii yoo bẹrẹ?
Eto idanwo ori ẹrọ ayelujara kọmputa CBT fun awọn akẹkọọ agbele ṣedanwo iwe mẹwaa WASSCE yoo bẹrẹ ni oṣu keji ọdun 2024.
Eyi ni ajọ WAEC sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita.
Lati ọdunmọdun ni ajọ WAEC ti maa n ṣeto idanwo meji lọdọọdun.
Akọkọ ni ti awọn awọn akẹkọọ oniwe mẹwaa ti wọn wa ni kilasi kẹfaa ni ile ẹkọ girama.
Ti ikeji si jẹ ti awọn akẹkọọ agbeleṣedanwo iwe mẹwaa ti ọpọ mọ si GCE eleyii to maa n waye losu kẹwaa si ikọkanla lọdọọdun.
Amọṣa pẹlu ikede tuntun yii, akoko idanwo awọn akẹkọọagbele ṣedanwo GCE naa ti yipada bayii.
Bawo ni idanwo kọmputa CBT naa yoo ṣe ri?
Ajọ Waec sọ wi pe ibeere eyi jẹ eyi o jẹ (Objective tests) yoo waye patapata lori ẹrọ ayarabiaṣa kọmputa.
Nigba ti awọn alakọsilẹ Essay ati ayẹwo Practicals yoo waye lọna igbalode ‘hybrid’
Ohun ti eyi tumọ si ni pe wọn ko ni lo iwe fun ibeere rara bi o ti wulẹ ko mọ lasiko idanwo naa.
Bakan naa ni yoo jẹ wi pe ori fọnran ni wọn yoo kọ gbogbo awọn ibeere naa si ti wọn yoo si pin iwe idahun fun awọn akẹkọọ.
Awọn akẹkọọ yoo si kọ idahun ti wọn ni fun ibeere kọọkan sinu iwe idahun ọwọ wọn.
Nibo lawọn idanwo yii yoo ti wa maa waye o?
Ajọ Waec sọ pe awọn ilu nlanla ni ibudo idanwo yii yoo wa kaakiri orilẹede Naijiria, nibẹ si ni awọn akẹkọọ yoo maa lọ lati joko ṣe idanwo wọn.
Ni oṣu kejila ọdun 2023 ni iforukọsilẹ fun idanwo yii yoo bẹrẹ
Bakan naa ni ajọ ọhun ni awọn ti ṣeto fun idanwo igbaradi ‘mock’fun awọn akẹkọọ to ba fẹ ni oye nipa bi eto idanwo naa gangan yoo ṣe ri.
Eyi fihan pe gbogbo akẹkọọ to ba fẹ joko ṣe idanwo yii gbọdọ kọ nipa lilo ẹrọ ayarabiaṣa kọmputa yekeyeke.












