Orí Facebook ni olójú àánú ti rán mi nílé ẹ̀kọ́ – Akẹ́kọ̀ọ́jáde UNILORIN tó ní ‘first class'
Ọdọkunrin kan ti oloju aanu gbe bukata owo ile ẹkọ rẹ lati ori ayelujara, to si jade pẹlu ipo kinni, Busari Taiwo, ti tu pẹrẹpẹrẹ irinajo aye rẹ fun BBC.
Ọdọkunrin naa ni lati ilẹ pẹpẹ ni oun ti jẹ ẹni to fẹran lati maa kawe, koda ipele kẹta nile ẹkọ alakọbẹrẹ ni oun ti maa n kawe loru ọganjọ, ti ibaba oun ko si mọ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ṣoro lati lọ sile ẹkọ lẹyin iku baba rẹ to waye lọdun 2010.

Oríṣun àwòrán, bbc
Inu ọkọ ni mo ti pade oloore mi

Oríṣun àwòrán, Tunde Lekan Olatunji
Taiwo sọ fun BBC pe ọjọ kan ti oun n lọ sile ẹkọ naa niluu Iorin ni oun pade arakunrin kan ninu ọkọ, ti awọn si bẹrẹ itakurọsọ.
O ni “Ko to di pe mo wọ ile ẹkọ naa ni mo pade ẹni to n jẹ Ojewola Olawale ninu ọkọ.”
“Emi ati ẹni yẹn, a jọ ni itakurọsọ... ẹni yẹn wa n bi mi pe ki ni mo gba ninu idanwo JAMB mi, mo wa sọ pe 294.”
“Ẹni yẹn wa n bi mi lere pe ṣe mo ti ni ẹnikan ti yoo ran mi lọwọ lati kawe ni tabi mo ni awọn ẹbi to fẹ ran mi lọ sile ẹkọ, mo wa ni mo ni Ọlọrun.”
Ọgbẹni Olawale lo fi ọrọ mi sori Facfebook ti mo fi ri oluranlọwọ

Oríṣun àwòrán, bbc
Taiwo sọ siwaju si pe ọgbẹni ti oun pade ninu ọkọ naa lo fi ọrọ oun sori Facebook, eyii ti alaanu kan ri, to si gbe igbesẹ lati san owo ile ẹkọ oun.
Ọrọ yii ti ọgbẹni Ojewola fi sori Facebook ni Họnọrebu kan, Tunde Lekan Olatunji ri, to fi san owo ọdun kan akọkọ nile ẹkọ naa.
Taiwo ni “Emi tilẹ ro pe o ti pari sibẹ ni, nitori nigba ti Ọlọrun ti ba mi ṣe ti mo ti ri owo ile ẹkọ san, emi ti wo o pe ka maa rọra maa tẹ iyoku jẹjẹ....”
“Ibẹ ni wọn ti wa sọ fun mi pe awọn maa ri daju pe awọn ṣugba mi titi mo fi ṣetan, ti wọn si mu adehun wọn ṣẹ .”
“Fun gbogbo ọdun mararun ti mo lo ni fasiti ti o jẹ pe awọn lo san owo ile ẹkọ mi.”
Taiwo pari ọrọ rẹ pe aburu ati ire lo wa lori ẹrọ ayelujara amọ ori ayelujara loun ti pade oloju aanu to san owo ile ẹkọ oun lati ibẹrẹ titi de opin lai mọ oun ri ṣaaju.



