Fídíò réè tó ṣàfihàn bí àwọn eèyàn Gaza ṣe já wọ ibùdó tí wọ́n kó nkan ìrànwọ́ sí

Àkọlé fídíò, Gaza War:Fídíò réè tó ṣàfihàn bí àwọn èèyàn Gaza ṣe já wọ̀ ibùdó tí wọn kò nkán iranwọ sí

Bi a ko ba nilo iranwọ yi ni a ko ni ja wọ ibi ti wọn ko si lati ko nibẹ.

Esi ree ti ọkan lara awọn ọdọ ilu Gaza ni Palestine fọ lasiko ti awọn eeyan ilu naa yabo ibudo iko nkan iranwọ pamọ si lọjọ Abamẹta to kọja.

Niṣe lawọn eeyan ilu naa lọkunrin lobinrin lọmọde ati agba ja ilẹkun abawọle ti wọn si n ko awọn nkan ounjẹ to wa ni ibudo ajọ isọkan agbaye UN.

Lẹnu igba ti ogun bẹ silẹ ti orileede Israel si ti di awọn araalu Gaza mọle ti ko si ina mọnamọna ati omi, niṣe lawọn ijọba ati araalu jakejado agbaye n ke si wọn lati dẹ okun ijiya yi fawọn araalu Gaza.

O le ni miliọnu meji eeyan ti ọpọ ninu wọn jẹ ọmọde ati ọdọ to kora jọ sinu aaye ilẹ ti wọn wa ni Gaza.

Israel lawọn n gbe igbesẹ yi lati fi koju ikọ Hamas to kọju ija si awọn ọmọ orileede Israel ti wọn si tun ko awọn eeyan kan si ahamọ.

Ida marun un ida ọgọrun iye omi to yẹ ki wọn ri lo lawọn eeyan ilu Gaza n ri bayii nitori ti Israel ti ti omi to n lọ si ilu naa pa.

Eyi mu ki ajọ ilera lagbaye maa ke gbajare pr ewu nla ni eyi jẹ tori o le ṣokunfa iku awọn ọmde bi wọn ko ba ri omi mu.

Bakan naa ni ajọ WHO sọ pe airi omi to da mu n ṣokunfa ki awọn ọmọ yi maa ṣe aarẹ.