Àwòrán bí ó ṣe ń lọ rèé níbi ìsìnkú àwọn èèyàn Israel tó bá ìkọlù Hamas lọ
Israel tẹsiwaju pẹlu eto isinku awọn eeyan rẹ to ba ikọlu ikọ Hamas to waye lọjọ Keje oṣu Kẹwaa lọ.
Nibi ikọlu yi la ti ri tawọn ikọ Hamas yabo agbegbe Israel ti wọn ṣi ṣe ikọlu sawọn eeyan nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Dan Kitwood/Getty Images
Eeyan 1,400 lo ku ninu ikọlu yi ti awọn ikọ Hamas si ko eeyan 230 lẹru ogun.
Ayẹyẹ isinku kan waye ni ọjọ Aiku fun ọmọ obinrin ọdun mẹsan an kan Tamar Chaya Torpiashvili ti ijaya gbigbọ to gbọ ariwo ikilọ pe awọn ado oloro n bọ lati Gaza si Israel ṣokunfa iku rẹ.

Oríṣun àwòrán, REUTERS/Ronen Zvulun
Baba ọmọ naa Avraham sọ lẹyin igba ti wọn sinku ọmọ rẹ tan pe:
"Ko ṣadede ku.Bẹẹ ko papoda. Wọn ṣekupa a ni.''
Ariwo feere ikilọ to gbọ lo ṣekupa.Kii ṣe ibọn, bẹẹ kii ṣe ọbẹ.Ariwo feere.Ohun ni wọn lo lati fi gba ẹmi ọmọ ọdun mẹsan an''

Oríṣun àwòrán, Dan Kitwood/Getty Images

Oríṣun àwòrán, Dan Kitwood/Getty Images

Oríṣun àwòrán, REUTERS/Ronen Zvulun








