Israel-Gaza war:‘Páropáro lojú òpó Whatsapp ẹbí wa dá,gbogbo wọn tí ku’

Oríṣun àwòrán, Ahmed Alnaouq
- Author, Stephanie Hegarty
- Role, BBC World Service Population reporter
Ago mẹrin idaji ni Ahmed taji loju oorun.
O jẹ ẹni to maa n sun wọra amọ ara ro fun lo fi ta ji lasiko yi.
Lati igba ti ogun bẹrẹ laarin Israel ati Gaza ko sinmi lati maa yẹ oju opo Whatsapp awọn ẹbi rẹ wo.
O nira lasiko yi ko to le ribi gburo baba rẹ ati awọn ọmọ iya rẹ ni London to n gbe.
Ko sẹyin bi Israel ti ṣe ge ina mọnamọna kuro fawọn eeyan Gaza.
Amọ ninkan bi ọjọ meji sẹyin, o gburo ọmọ iya rẹ obinrin Wallah.
Ado oloro ti wo ile rẹ.
Wallah fi ọrọ ranṣẹ soju opo Whatsapp ẹbi wọn pe''Awọn ferese ati ilẹkun ile lo ti fọ danu.A kan ṣaa dupẹ pe Ọlọrun yọ wa.Alaafia ni gbogbo wa wa''
Ahmed da esi pada fun to si ni ''A yi le ṣatunṣe ile.Pataki julọ ni pe ẹ wa daada.''
Wallah ati awọn ọmọ rẹ mẹrin ko lọ si ile baba wọn to wa ni Deir al-Balah laarin Gaza.
Loru ọj ti Ahmed ṣadede taji yi,paroparo loju opo Whatsaap ẹbi da.O ri awọn ọrọ tawọn kan ju sibẹ amọ ti wọn tun pa wọn rẹ pada.
Ki lo le maa ṣẹlẹ?
O pe ọrẹ rẹ kan to wa ni Gaza lori ago lati ṣei iwadii.
Igba naa lo to mọ wi pe gbogbo ẹbi rẹpata lo ti ku.

Oríṣun àwòrán, Ẹbi Alnaouq
Lati igba ti ogun ti bẹrẹ, nkan ko rọgbọ fun Ahmed ati awọn alabagbe rẹ ti wọn jijọ wa lati Gaza .
Foonu alagbeka wọn si ti da bi irinṣẹ iro ibanujẹ ohun iku fun wọn.
Ojumọ kan ko ni mọ ki wọn ma gburo pe alabagbe kan, ọrẹ tabi eeyan ti wọn jijọ lọ ile ẹkọ papọ kan ti dagbere faye.
Tohun ti gbogbo rẹ, Ahmed ko lero pe ogun yi yoo wa de ba oun naa gbọngbọn bayii.
Laarin Deir al-Balah ni ile wọn wa ti wọn o si ṣe ikọlu si agbegbe naa ri.
''Ohun ti mo ro pe pe asiko yi kan le maa ja wọn laya nikan ni.''
Lapapọ eeyan mọkanlelogun ninu ẹbi rẹ ni ado oloro parẹ mọ ile wọn.
Baba rẹ, ọmọ iya rẹ obinrin mẹta, ọkunrin meji ati awọn ọmọ wọn mẹẹdogun.

Oríṣun àwòrán, Alnaouq family
Iye awọn to ku pọ debi pe Ahmed a maa kalolo to ba bẹrẹ si ni pe orukọ ati ọjọ ori awọn to padanu ẹmi wọn ninu mọlẹbi rẹ.
Ninu awọn ọmọde to ku,ọmọ ẹgbọn rẹ Eslam to jẹ ọmọ ọdun mẹtala loun ati Ahmed sunmọ ara wọn julọ.
Nigba ti Ahmed naa ṣi wa ni ipo ọdọlangba ni wọn bi ọmọ yi ninu ile ti wọn jijọ n gbe pẹlu obi rẹ.
Iya Ahmed lo maa n ba wọn tọju Eslam ti mama rẹ ba lọ si ibiṣẹ.
Koda Ahmed naaa maa ba wọn gbe jo nigba to wa ni ikoko.
Bi Eslam ṣe n dagba lo sọ pe o wu u lati dabi aburo iya rẹ iyẹn Ahmed.
Eslam jẹ ọmọ to gbaju mọ ẹkọ rẹ to si mura si ẹkọ ede Gẹẹsi ki o ba le lọ ba ''Uncle'' rẹ Ahmed ni ilẹ Gẹẹsi
Eslam ati awọn aburo rẹ -Dima,ọmọ ọdun mẹwaa,Tala ọmọ ọdun mẹsan,Nour ọmọ ọdun marun un ati Nasma ọmọ ọdun meji ni wọn jijọ padanu ẹmi wọn.
Awọn ibatan wọn mii naa padanu ẹmi wọn.
Raghad ọmọ ọdun mẹtala,Bakr, ọdun mọkanla, Eslam ati Sarah ọmọ obinrin ọdun mẹsan an, Mohammed ati Basema ọmọ ọdun mẹjọ ati Abdulahh ati Tamim ti wọn jẹ ọmọ ọdun mẹfa.

Oríṣun àwòrán, Alnaouq family
Loju opo ipe ori fidio ni Ahmed ti ri wọn kẹyin.
Wọn fun ni owo moriwu nibi iṣẹ rẹ to si ṣadehun lati fi ra nkan fawọn ibatan rẹ.
''Gbogbo wọn sọ pe eti omi okun lo wu awọn la ti lọ ṣe faaji majemamu.Mo si fi owo ranṣẹ ki wọn baa le fi ṣe eto gbogbo''
Gbogbo awọn ọmọ yi lo pe lati ibi igbafẹ wọn ti wọn si n fa foonu mọ ara wọn lọwọ lati le fi baa sọrọ.
Gbogbo awọn ọmọ mẹẹdogun yi lo tipadanu ẹmi wọn..
Ninu awọn ọmọ iya Ahmed, oun ati awọn ọmọ iya rẹ obinrin meji pere lo ṣẹ ku.
Lẹyin igba ti ikọlu yi waye,niṣe ni Ahmed bẹrẹ si ni fi aworan ọkọọkan ninu awọn ọmọ yi soju opo aytelujara to fi mọ ti Omar to jẹ ọmọ ọdun mẹta.
Ko pẹ sigba naa lo gba ipe lati ọdọ ọmọ iya rẹ lobinrin to sọ pe 'Omar ko ku.
''Ọjọ yi jẹ ọjọ to mu ninu mi dun jul laye''
Omar wa lori ibusun pẹlu iya ati baba rẹ,Shimaa ati Muhammed nigba ti ado oloro re lu ile wọn.
Muhammed to jẹ baba rẹ ku ṣugbọn ori ko Omar ati iya rẹ yọ .
Eeyan kan ti wọn tun ri yọ jade labẹ ile ti wọn yin ado oloro lu ni Malak to jẹ ibatan Ahmed.
Ọmọ ọdun mọkanla yi la gbọ pe ina jo ida meji ninu ara rẹ.

Oríṣun àwòrán, Alnaouq family
Nigba ti mo ba Ahmed pade o fi aworan Malak han mi nigba to wa ni ile iwosan.
Gbogbo ara rẹ ni wọn we ni bandeeji.
Mo kọkọ ro pe ọmọ ọkunrin lo wa ninu aworan naa nitori irun ori rẹ ko pọ afi igba ti Ahmed sọ fun mi pe ina lo jo irun rẹ.
Baba Malak ko si ninu ile naa nigba ti ibugbamu yi waye.
Amọ iyawo rẹ ati awọn ọmọ wọn meji padanu ẹmi wọn .
Nigba ti Ahmed kan si lati beere pe boo wa ni nkan ri lọdọ rẹ o lo sọ pe ''Kolofo lasan lo ku, ko si ẹmi lara mi mọ''
Nigba naa lọhun,wọn ti ge gbogbo oju opo ibaraẹnisọrọ ni Gaza.
Ati ribi ba eeyan sọrọ jẹ iṣoro nla.
Nigba ti wọn yoo fi ribi kan si ara wọn ni Ahmed to gbọ pe Malak ti pada ku.
Aisi oogun lati fi tọju rẹ jẹ iṣoro nla.
Wọnni lati gbe Malak kuro lori ẹrọ ICU nigba ti ẹlomiran ti iṣoro tiẹ pọ ju tiẹ lọ de si ile iwosan.
Baba rẹ sọ fun Ahmed pe ''ojojumọ ni inu mi n bajẹ lati maa ri ọmọ mi titi ti ẹmi fi pada bọ lara rẹ.''
Gbogbo awọn ọmọ rẹ mẹtẹẹta lo pada ku mọọ loju.

Oríṣun àwòrán, Alnajjar family
Ki gbogbo nkan to pa lọọlọ,bakan naa ni iroyin de si eti igbọ Ahmed wi peado oloro kọlu ile ẹgbọn baba rẹ.Ko yi ti mọ awọn to padanu ẹmi wọn nibẹ.
A ba eeyan mẹta to padanu mọlẹbi to le ni ogun ni Gaza sọrọ.
Ọkan ninu wọn Darwish Al-Manaama padanu mọlẹbi mẹrinlelogoji.
Ajalu nla lo de ba idile wọn.
Yara Sharif onimọ nipa ile yiya to si tun jẹ olukọ ni London fi awọn aworan ile ẹgbọn baba rẹ lobinrin ti ikọlu Israel ṣe akoba fun .
''Ile to rẹwa pupọ ni ile yi to si ni ọgba laarin.O jẹ ile ti awọn ọmọ wọn ọkunrin naa kọ ile wọn sori ti awọn obi wọn gẹgẹ bi aṣa wọn nibẹ.Eyi tunmọ si pe aimọye eeyan lo ba ado oloro to jabọ lu ile naa lọ''

Oríṣun àwòrán, Alnajjar family
Eeyan oku lo padasnu ẹmi wọn ninu ikọlu yi.
Ẹgbọn baba Yara lọkunrin ati obinrin, awọn ibatan rẹ meji ati awọn ọmọ wọn mẹwaa ati awọn mọlẹbi wọn mẹfa mii.
Abẹ ile to wo ni wọn ti fa oku wọn yọ ti ẹka ileeṣẹ ilera Gza si ka wọn mọ orukọ awọn aimọye to padanu ẹmi wọn ti ko lorukọ.
Yara fi aworan akojọpọ orukọ yi ti wọn si fa ila ami pupa ṣẹgbẹ orukọ kọọkan.
Lapa ọtun, ọjọ ori wọn wa nibẹ, Sama ẹni ọdun mẹrindinlogun, Omar ati Fahmy jẹ ibeji ọmọ ọdun mẹrinla,Abdul jẹ ọmọ ọdun mẹtala,Fatimah, ọdun mẹwaa, Obaida, ọdun meje Aleman ati Fatima ọmọ ọdun marun un, Youssef ọmọ ọdun mẹrin, Sarah ati Anas to jẹ ọmọ ọdun mẹta.
Yara ni awọn ibatan meji ti o ṣẹku bayii.Wọn ni ka ma darukọ wọn nitori ibẹru pe awọn to ba ba akọroyin sọrọ wa ninu ewu ki wọn foju si wọn lara.
Awọn ibatan meji yi wa lapa ibomiran ni Gaza mi o si ribi kan si wọn boya ka tiẹ ba ra wa kẹdun tabi ka di ara wa mu nibi isinku.

Oríṣun àwòrán, Alnajjar family
Ko si epo ti wọn yoo fi lo awọn irinṣẹ ti awọn adoola n lo lati fi yọ awọn to ha sabẹ ile to wo.
Lọjọ Ẹti ti emi ati Ahmed n wo iroyin lori ẹrọ amohunmaworan, a ri ti wọn ṣafihan orukọ awọn ti o padanu ẹmi wọn loju iran wa.
Mo beere pe ṣe orukọ awọn ẹbi rẹ wa nibẹ.
O ni ''awọn mejila pere lo wa nibẹ''
O ni wọn o ti ri awọn mẹsan to ku.
Lọsẹ to kọja ẹgbọn rẹ obinrin to wa ni ile rẹ nigba ti ado oloro yi ja lu wọn lọ ṣe abẹwo si awọn ile tofarapa iṣẹlẹ yi.
O sọ fun Ahmed pe oun ko pẹ nibẹ tori oorun oku awọn to ha sabẹ ile ko jẹ koun gbadun.
Lati ọjọ Ẹti Ahmed ko yi ti ba ikankan sọrọ ninu awọn ọmọ iya rẹ obinrin.
Foonu wọn ko ṣiṣẹ ko si mọ nkan to n ṣẹlẹ si wọn.

Oríṣun àwòrán, Alnaouq family
Ninu awọn to ku ni aburo Ahmed Mahmoud wa.
O ti fi igba kan ba ajọ ẹlẹyinju aanu kanna ti Ahmed n ba ṣiṣẹ ti orukọ rẹ n jẹ ''We are Not Numbers''
Mahmoud ṣẹṣẹ ri eto ẹkọ ọfẹ gba lati tẹsiwaju ẹkọ rẹ ni Australia.
Ọsẹ kan lẹyin ti ogun yi bẹrẹ lo sọ fun Ahmed wi pe oun ko fẹ lọ ati pe inu oun ko dun si bi awọn ileeṣẹ iroyin ṣe n gbe iroyin nipa ikọlu si Gaza to n waye.
O kọ soju opo rẹ ni Twitter pe ''Ẹmi mi o gbe mọ. Niṣe ni wọn n pa wa ni ipakupa''
Ọsẹ kan leyin igba to kọ ọrọ yi lo kagbako iku ninu ile baba rẹ ti wọn sọ ado oloro si.
Ahmed nigba to n sọrọ nipa baba rẹ ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹlẹyinju aanu eeyan.O lo jẹ alakitiyan to n wa takisi to si tun n ṣe iṣẹ awọn to n kọ ile.
O ni ibẹ lo ti ri owo fi kọ ile fun mọlẹbi rẹ to si tun ran awọn ọmọ rẹ lẹkọ.
O ni a maa gbọ iroyin ni gbogbo igba to si tun ni igbagbọ pe ọna abayọ si gbogbo hilahilo yi ni pe ki wọn da orileede kan silẹ fun Israel ati awọn eeyan Palestine lati maa jijọ gbe papọ.












