Irinṣẹ́ rọ́bọọ́ọ̀tì tó ń ṣe bí èèyàn pa òṣìṣẹ́ tó ń darí ẹ̀

Oríṣun àwòrán, GOOGLE
Jegejege ni irinṣẹ oyinbo ti wọn ṣe bi èèyàn (Robot) run ọkùnrin kan to n dari rẹ lẹnu iṣẹ l'Ọjọruu ọsẹ yìí, paali ẹfọ ati oúnjẹ lasan to n ko lo fi oṣiṣẹ náà pe to fi run ùn pa.
Ẹka iroyin Yonhap, ni South Korea tiṣẹlẹ yii ti waye, ṣalaye pe lasiko ti oṣiṣẹ naa n yẹ iṣẹ rọbọọti ọhun wo bo ṣe pe sí, ni kínní náà gbe é to si run mọ bẹliiti to wa nibẹ.
Iṣẹ ti wọn fẹẹ maa lo irinṣẹ ti wọn ṣe bi èèyàn náà fún ni pe kó máa ko àwọn ounjẹ bíi ata, ẹfọ ati bẹẹ bẹẹ lọ kò sí máa ju wọn sí ààyè wọn.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wí, oju ati àyà okunrin naa lo faragba ijamba náà ju, nitori irinṣẹ to gbe e náà ṣe e bo ṣe máa n ṣe awọn paali ounjẹ to ba gbe ni.
Alẹ nijamba ọhun waye, wọn sì sáré gbe okùnrin náà lọ sileewosan, ṣugbọn iku lo já sí.
Ẹni ogoji ọdun lọkunrin to pade iku ojiji lẹnu iṣẹ yii, ileeṣẹ to ti n ṣiṣẹ naa lo si ṣe ẹrọ to pa ọhun.
Ìròyìn sọ pé ọkunrin kan náà ha sẹnu rọbọọti loṣu kẹta ọdun yii, o fara ṣeṣe pupọ lasiko to n lo o fún ẹya ara mọto kan.








