Ìdí tí mo fi wọ fásitì lẹ́ni ọdún 64, ti mo sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè MSc lẹ́ni ọdún 72
Iya agba ẹni ọdun mejilelaadọrin to ṣẹṣẹ kẹkọọ gboye MSc, Mabel Ayodele Ayodeji, ti ṣalaye fun BBC Yoruba eredi to ṣe fi ewu ori kawe.
Iya agba naa wa lara awọn to ṣẹṣẹ ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade ni Fasiti aladani Crescent, to wa niluu Abeoukuta, nipinlẹ Ogun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ fun BBC, ko ni anfani lati kawe ni ibẹrẹ pẹpẹ aye rẹ lasiko ti awọn akẹgbẹ rẹ n kawe, amọ ko sọ ireti nu lori ọrọ iwe.
Iṣẹ ọmọ ọdọ ni mo n ṣe ni ibẹrẹ pẹẹ

Oríṣun àwòrán, bbc
O ni “Awọn akẹgbẹ, bi a ṣe pari ipele ‘modern 3’ bayii, eyii to gba ile ẹkọ girama lọ, eyii to gba ile ẹkọ awọn nọọsi lọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.”
“Emi nikan, mo wa lọ ṣe ọmọ ọdọ, ka fọ abọ, ka ro ọka, ka fun awọn onibara lounje... nnkan ti mo kọkọ bẹrẹ si n ṣe niyẹn.”
O ni iwọsi to wa nidi iṣẹ ọmọ ọdọ naa pọ to bẹẹ ti oun fi kuro nipinlẹ Ondo ti won bi oun si tẹkọ leti lọ siluu Ibadan.
Idi ti mo ṣe pinnu lati kawe

Oríṣun àwòrán, bbc
Iya agba naa ṣalaye pe ọkan lara awọn olukọ oun kan sọ fun oun lọpọ ọdun sẹyin pe oun gbagbọ pe oun yoo ṣi di ọjọgbọn lọjọ iwaju nitori oun jẹ ẹni to mọ iwe daadaa.
“Ni ọdun 1965... olukọ mi kan, nile ẹkọ ‘modern 3’ ti mọ lọ, wọn n pe orukọ rẹ ni Gabriel Babatunde Ojo.”
“O ni ki a ṣe idanwo kan, nigba ti a ṣe idanwo naa tan, o gba iwe mi to si maaki rẹ, o ni Ayo Aregbesola... mo ni ireti pe mo le pada wa si ilu Igabra Oke yii lọdun mẹwaa si asiko yii ki awọn eeyan dẹ sọ fun mi pe o ti di Ọjọgbọn nitori pe o jẹ ọmọ to ja fafa.”

Oríṣun àwòrán, bbc
“Titi di oni yii, ti mo ba n rin lọ, ọrọ naa maa n wa si ọpọlọ mi pe mo gbọdọ di Ọjọgbọn.”
Ọdun 2021 ni , Mabel Ayodele Ayodeji, kẹkọọ gbooye Bachelors Degree rẹ ni fasiti kan to wa niluu Cotonou lẹyin to ti ṣe iṣẹ ijọba fun ọpọlọpọ ọdun.
O pari ọrọ rẹ pẹlu amọran pe ko rọrun lati fi ewu ori kawe amọ ẹni to ba wa ni irufẹ ọjọ ori oun to si fẹ pada sile ẹkọ le gbe igbesẹ naa ti agbara rẹ ba gbe.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti iya agba yii ba BBC Yoruba sọ.



