Òṣìṣẹ́ ilé aṣòfin Oyo bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì wọn sọ àgádagodo sí gbogbo àbáwọlé

Aworan awọn oṣiṣẹ ile aṣofin ipinlẹ Oyo

Gbogbo ẹnu ọna abawọle ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ lo di titi pa l'owurọ ọjọ Aje.

Ko si ṣẹyin iyanṣẹlodi alainigbedeke ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ile aṣofin orilẹede Naijiria, 'Parliamentary Staff Association of Nigeria (PASAN)', ẹka ti ipinlẹ Ọyọ gunle.

Ọkanojokan akọle ti wọn mu lọwọ ati orin ti wọn n kọ lo n tọka awọn ẹdun ọkan wọn ati gbogbo ohun ti wọn n beere fun.

Awọn oṣiṣẹ naa sọ pe iyanṣẹlodi yii waye nitori ọjọ ti lọ lori adẹhun ti awọn alaṣẹ ṣe pẹlu ẹgbẹ PASAN ati awọn nnkan mii ti ẹgbẹ naa n beere fun n'ipinlẹ Ọyọ.

Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ nibi ifẹhonuhan to waye, alaga ẹgbẹ PASAN n'ipinlẹ Ọyọ, Arakunrin Yemi Alade ṣe alaye wi pe awọn oṣiṣẹ ile naa n pe fun imuṣẹ anfani fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ lati maa da ṣe eto iṣuna ara wọn.

Ohun ti wọn beere fun

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ile ke si Gomina Seyi Makinde lati tẹle aṣẹ to n bẹ ni isọri kọkanlelọgọfa (3a, 3b and 4a) ofin ilẹ wa ti ọdun 1999 (gẹgẹ bi wọn ti ṣe atunṣẹ rẹ).

Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ naa n pe fun imuṣẹ adehun ti wọn ṣe fun agbeyẹwo owo oṣu awọn oṣiṣẹ ile igbimọ aṣofin, 'Consolidated Legislative Salary Structures (CONLESS)'.

Nnkan mii ti wọn tun n beere fun ni sisan awọn ajẹmọnu wọn, ki o si pe ida ọgọrun.

Siwaju sii, ẹgbẹ PASAN n'ipinlẹ Ọyọ n pe fun atunṣe ofin iṣakoso ti wọn tọka si wi pe o tako itọju awọn oṣiṣẹ.

Ko tan sibẹ, wọn tun pe fun ifidimulẹ abadofin to n ri si amojuto awọn oṣiṣẹ ijọba gẹgẹ bi wọn ṣe gbe kalẹ l'ọdun 2023.

Aworan awọn oṣiṣẹ ile aṣofin ipinlẹ Oyo

Alade ṣe alaye fun awọn oniroyin wi pe iyanṣẹlodi naa yoo tẹsiwaju, bẹẹ sini awọn ẹnu ọna abawọle si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ yoo jẹ titi pa, titi ti awọn nnkan ti wọn n beere fun yoo fi di mimu ṣẹ.

L'opin ọsẹ ti o kọja ni alaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ọyọ, awọn aṣoju alaṣẹ ile igbimọ aṣofin lorilẹede Naijiria ati adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Adebo Ogundoyin ṣe ipade pọ pẹlu awọn aṣoju apapọ ẹgbẹ PASAN lorilẹede Naijiria.

Ṣugbọn aiso eso ire ipade naa lo ṣokunfa rogbodiyan ati iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ bayii

Lati ibẹrẹ ọdun ti a wa yii ati saaju asiko yi ni iroyin ti n waye nipa iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ ile igbimọ aṣofin lorilẹede Naijiria.

Ninu oṣu kaarun ọdun yii ni awọn oṣiṣẹ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun naa gunle iyanṣẹlodi lati beere fun ẹtọ wọn lọwọ ijọba.

Ninu oṣu kẹfa ọdun 2021, jakejado orilẹede yii ni awọn oṣiṣẹ ile aṣofin Naijiria, PASAN gunle iyanṣẹlodi lati beere fun ẹto wọn.