Ìjà tí Wike ń bá gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers jà ni yóò fa ìṣubú rẹ̀ - Primate Ayodele

Oríṣun àwòrán, Instagram: Wike/Primate Ayodele
Oniruru ọrọ lo ti n jade lẹyin ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Rivers ti bẹrẹ igbesẹ lati yọ gomina ipinlẹ naa, Siminalayi Fubara nipo.
Lara awọn to ti sọrọ nipa iyọnipo naa ni pasitọ agba ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Ayodele.
Ṣaaju ni gomina Fubara ti kọkọ fẹsun kan awọn ọlọpaa ipinlẹ naa pe wọn kọlu oun lọna ti ko ba ofin mu.
Lẹyin naa lo ni oun ko bẹru iyọnipo ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin naa n gbero rẹ si oun amọ wọn gbọdọ sọ fun gbogbo araalu ẹṣẹ ti oun ṣe ti wọn sẹ fẹ yọ oun nipo.
Ẹwẹ, ọpọ aralau lo gbagbọ pe wahala to n waye laarin gomina ọhun ati gomina to ṣaaju rẹ, Nyesom Wike lo ṣokunfsa igbeṣe iyọnipo naa.
Ija ti Wike n ba Fubara ja ni yoo fa iṣubu rẹ – Ayodele
Nigba to n da si ọrọ naa, alufaa agba ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Ayodele sọ pe ija ti Wike n Fubara yoo din agbra rẹ ku, yoo si sọ di ẹni yẹpẹrẹ.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ pasitọ ọhun, Oluwatosin Osho fi lede, Ayodele sọ pe ọrọ naa ni yoo fa iṣubu Wike ninu eto oṣelu Naijiria.
Wolii naa gba gomina Fubara ni amọran lati wa oju Ọlọrun lori ọna ti yoo gba lati yanju aawọ oun ati Wike, to jẹ gomina ipinlẹ Rivers ṣaaju rẹ.
O ni “Nigba ti mo sọ pe awọn gomina kan yoo ba awọn aṣaaju ja, awọn kan ti wọn ko mọ ohun ti mo n sọ ni wolii oṣelu ni mi, amọ wọn ko mọ pe ko si ohun to n jẹ wolii oṣelu, wolii ni wolii n jẹ.”
“Mo sọ pe ija yoo waye laarin Fubara ati Wike awọn eeyan ro pe ko le ṣeeṣe amọ ni bayii o ti ṣẹlẹ.”
“Ija yii yoo yẹyẹrẹ Wike, agbara rẹ yoo dinku, ko ni le ri oorun sun, mo si ri pe ija yii yoo din agbara oṣelu Wike ku.”
“Fubara gbọdọ wa oju Ọlọrun lati mọ ohun to yẹ ko ṣe nipa Wike nitori ko si ẹni ti yoo le yanju ija yii.”
“Wike ko ni pada lẹyin Fubara titi ti yoo fi rẹyin rẹ.”
Ohun tí a mọ̀ rèé lórí ọ̀rọ̀ gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers tí àwọn aṣòfin fẹ́ yọ nípò

Oríṣun àwòrán, @SimFubaraKSC
Awọn ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti fi gaasi tajutaju le awọn ọdọ to n ṣe iwọde lodi si iyọnipo gomina ipinlẹ naa, Siminalayi Fubara.
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ti ina sọ lapakan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa to wa niluu Port Harcourth.
Iroyin sọ pe nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii ni awọn kọlọrọsi kan lọ sọ ina ọhun sile igimọ aṣofin naa.
Wayi o, awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa ti gba inu ọgba ile igbimọ aṣofion naa bayii.
Ki ni ohu ti ṣẹlẹ bayii?
Ṣaaju ki awọn ọlọpaa to yin gaasi tajutaju naa ni awọn aṣofin ọhun ti kọkọ kede pe awọn yoo yọ gomina Fubara nipo.
Wọn tun yọ olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ ju ninu ile naa, Edison Ehie, lori ẹsun pe oun lo wa nidi ina to sọ nibẹ.
Yatọ si Ehie ti wọn jawe lọ gbele ẹ fun, wọn tun ṣe bẹẹ gẹgẹ fun awọn amofin mẹta mii.
Gomina Siminialayi Fubara lawọn ọdọ ti ọlọpaa yin gaasi tajutaju tẹle lọ sile igbimọ aṣofin naa lẹyin ti wọn ni awọn ko fẹ ki wọn yọ gomina ọhun nipo.
“Ọlọpaa ṣina ibon fun mi”
Wayi o, gomina Fubara ti fẹsun kan awọn ọlọpaa pe wọn yinbọn si oun.
Asiko to n ba awọn ololufẹ rẹ sọrọ ni gomina ọhun fi ọrọ naa lede.
O ni “A ji laarọ oni lati lọ si ọgba ile igbimọ aṣofin naa lati mọ ohun to ṣẹlẹ nibẹ.”
“Nigba ti mo lọ sibẹ, ọlọpaa yinbọn fun mi lojukoju....”
“Ti wọn ba yọ gomina Siminialayi Fubara nipo, kii ṣe emi ni gomina akọkọ ti wọn yoo yọ nipo, bẹẹ si ni kii ṣe emi ni gomina ti wọn yoo yọ nipo kẹyin.”
“Amọ a ko ni gba ki wọn ṣe ohunkohun ti ko lẹsẹ nilẹ... wọn gbọdọ ṣalaye fun awọn ipinlẹ Rivers ohun ti Fubara sẹ ti wọn sẹ fẹ yọ ọ nipo gomina.”












