Atiku kọminú lórí ìdájọ́ Supreme Court, o ní kò yẹ kí Tinubu dupò Ààrẹ rárá

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Alhaji Atiku Abubakar ti ní ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà gbé kalẹ̀ lórí ètò ìdìbò ààrẹ ọdún 2023 ti ṣàfihàn pé nǹkan kò lọ déédéé mọ́ Nàìjíríà.
Atiku ní Nàìjíríà nílò àtúntò gidi láti gbà á kalẹ̀ lọ́wọ́ kí ilé ẹjọ́ máa ṣe ẹjọ́ lórí àbájáde èsì ìbò, ní ohun tó yẹ kó jẹ́ pé ìfẹ́ àwọn olùdìbò ló yẹ kó máa ṣẹ.
Atiku sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Ajé, lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ipò rẹ̀ lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Supreme Court.
Ṣáájú ni Atiku ti pe ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ààrẹ ní ẹjọ́ tí Atiku pè tako ìjáwé olúborí Tinubu kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Lásìkò ìgbẹ́jọ́ ní Supreme Court ni Atiku ní òun fẹ́ fi ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ pé Tinubu yí ìwé ẹ̀rí tó ní òun gbà láti ilé ẹ̀kọ́ Chicago State University àmọ́ tí ilé ẹjọ́ kò gba ẹ̀rí rẹ̀ wọlé pé ó ti kọjá iye ọjọ́ tí òfin là kalẹ̀ láti gbé ẹ̀rí rẹ̀ síwájú ilé ẹjọ́.
Bákan náà ni ilé ẹjọ́ tún da ẹjọ́ tí olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi pè nù pé kò ní ẹ̀rí tó rinlẹ̀ láti fi gbe ẹjọ́ rẹ̀ lẹ́sẹ̀.
Atiku ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ohunkóhun tí òun lè ṣe mọ́ lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, ó ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè ni ìdájọ́ náà fi sọ́kàn àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Ó wòye pé ìdájọ́ náà ti sọ ìrètí àti ìgboyà àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú ètò òṣèlú àti pàápàá lórí àjọ tó ń mójútó ètò ìdìbò Nàìjíríà ìyẹn INEC nù.
Ó ní òun kò mọ ohun tó máa fún ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìwúrí láti tún dìbò lọ́jọ́ iwájú nígbà tó jẹ́ pé ìfẹ́ wọn kò ní wá sí ìmúṣẹ.
Atiku ní ìgbésẹ̀ yìí le ṣokùnfà kí ètò ìdìbò àwaarawa ní Nàìjíríà dojú délẹ̀ nítorí ilé ẹjọ́ kò fún àwọn ènìyàn láàyè láti yan olórí tó wù wọ́n mọ́.
Ẹ̀wẹ̀, àjọ tó ń mójútó ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC ní ètò ìdìbò tí kò lẹ́ja-n-bákàn nínú ni àwọn ṣe àti pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ ti wẹ àwọn mọ́.
Àsìkò ti tó fún Nàìjíríà láti máa ṣe Ààrẹ oní sáà kan
Atiku tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àsìkò ti tó fún àwọn Ààrẹ ní Nàìjíríà láti máa ṣètò ìjọba ọlọ́dún mẹ́fà tí wọn kò sì ní máa ṣe ju sáà ẹyọ̀kan péré lọ.
Bákan náà ló ní gbígbé Ààrẹ yípo ẹkùn mẹ́fẹ́ẹ̀fà tó sọ orílẹ̀ èdè yìí ká yóò mú ìṣọ̀kan àti ìlọsíwájú bá ètò òṣèlú.
Ó fi kun pé ìgbésẹ̀ náà yóò dín agbára àwọn olóṣèlú tó bá wà nípò kù àti pé kò ní jẹ́ kí wọ́n yẹ̀bá lórí iṣẹ́ ìlú tí wọ́n bá gbé dání.
Ó tẹ̀síwájú pé gbígbé ipò Ààrẹ káàkiri ẹkùn mẹ́fẹ́ẹ̀fà máa dín bí àwọn kan ṣe ń jẹ gàba lórí àwọn ẹkùn mìíràn tí wọn kò fún àwọn kan láàyè láti dé ipò náà.
Ó tún gba INEC ní ìmọ̀ràn láti máa ṣe àyẹ̀wò àwọn ìwé ẹ̀rí tí olùdíje bá gbé kalẹ̀ fún wọn wò fínnífínní nítorí ojúṣe wọn ní láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Atiku ní kò yẹ kó jẹ́ pé ẹgbẹ́ alátakò ni yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gba iṣẹ́ INEC ṣe láti fìdí ohun tó bá jẹ́ òótọ́ múlẹ̀.
Ó tẹ̀síwájú pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àsìkò ti tó fún àwọn ọ̀dọ́ láti gba àkóso orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Atiku ní òun kò ní lọ ibì kankan.
Ó ní òun máa rí dájú pé òun kó ipa tòun láti mú kí ìjọba àwaarawa fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀ dáadáa kí àtúntò sì bá Nàìjíríà.















