Tí mo bá r’ọ́kùnrin tó fẹ́ fẹ́ mí, mo ṣetán láti ṣe ìyàwó kejì - Wumi Toriola

Oríṣun àwòrán, Wumi Toriola/Instagram
Gbajumọ oṣerebinrin, Wumi Toriọla, ti ṣalaye pe oun ko kọ lati di iyawo keji nile ọkunrin to ba ṣetan lati foun ṣeyawo.
O ni ero toun n ro tẹlẹ pe oun ko le ṣeyawo keji ko ri bẹẹ mọ rara.
Lori eto kan ti Debbi Ṣokọya toun naa jẹ oṣere tiata maa n ṣe ni Wumi ti sọrọ yii. O ni ko si idi kan toun fi yi ero oun pada ju pe oun ki i ṣe ọlọmọge mọ.
Wumi ṣalaye pe nigba toun ti di ọlọmọ kan, ki loun yoo waa ma sọ pe oun ko le ṣeyawo keji mọ fun.
Gẹgẹ bi oṣere ọmọ Yewa nipinlẹ Ogun naa ṣe wi, ‘’tẹlẹ ni mo maa n ro pe mi o le ṣeyawo keji tabi ikẹta nile ọkọ, ṣugbọn gbogbo iyẹn ti yipada bayii lẹyin temi naa ti di ‘afta one’ (ọlọmọ kan).
‘’ Ti mo ba ri ọkunrin ọlọmọ kan bii temi, abi ẹni ti iyawo ẹ ti ku, mo maa fẹ ẹ. Ohun to ṣe pataki ni ki n ti ri idunnu nibẹ, idunnu mi lo ṣe koko.’’
Obinrin to saba maa n kopa oniwahala ninu ere sinima naa tẹsiwaju, pe ọpọ ọkunrin ni ki i kọnu ifẹ sawọn obinrin onitiata, nitori wọn maa n ro pe olowo nikan lo le fẹ wọn.
Wumi Toriọla sọ pe eyi ko ri bẹẹ rara, o ni ọpọlọpọ awọn oṣerebinrin yii lo jẹ pe iṣẹ ọwọ wọn ni wọn fi ko ọrọ̀ wọn jọ, ti ko si ọwọ ọkunrin nibẹ rara.
O ni ṣugbọn awọn eeyan maa n ro pe awọn baba olowo lo n gbe ọla si wọn lara ni.
Tẹ o ba gbagbe, ọdun 2018 ni Wumi Toriọla ṣegbeyawo pẹlu ọkọ rẹ, 2019 lo bimọ ọkunrin ti wọn pe ni Zion.
Ibẹrẹ ọdun 2023 yii ni igbeyawo naa fori ṣanpọn.















