Ṣé lóòtọ́ọ́ ni èèyàn kan kú níbi ìkọlù àwọn agbébọn àti fijilanté l'Oyo?

Oríṣun àwòrán, Other
Rogbodiyan bẹ silẹ lọjọ Aje ọsẹ yii, niluu Ṣẹpẹtẹri, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ṣaki, ipinlẹ Ọyọ, lasiko tawọn agbebọn ya wọ ode ariya kan ti si gbọ pe wọn ji eeyan meji gbe lọ nibẹ, ti wọn tun pa ẹnikan.
Itosi Igbo ọba atijọ (Old National Park) ni ayẹyẹ ọhun ti n waye gẹgẹ bi a ṣe fidi ẹ mulẹ, ojiji ni a gbọ pe awọn agbebọn ti wọn furasi pe Fulani darandaran ni wọn ya wọ ode ariya naa ti wọn si kọlu awọn eeyan.
Ikọlu yii lo mu awọn fijilante agbegbe naa koju awọn agbebọn ọhun ti wọn si le wọn wọnu igbo naa.
Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn fijilante naa ṣe ṣalaye, iyẹn Elisha Ọlanrewaju, o ni ‘’a wọnu igbo naa tẹle wọn, a si gba ẹnikan silẹ ninu awọn ti wọn ji gbe.
‘’Bi wọn ṣe ri wa ni wọn bẹrẹ si i yinbọn si wa, nigba to ya ni wọn gba ọna Iṣẹyin sa lọ.
A dupẹ pe ko sẹni to ku ninu wa nigba ti wọn doju ibọn kọ wa.’’
Ẹnikan to kọ lati darukọ rẹ ṣalaye pe agbegbe igbo ọba atijọ yii ni awọn agbebọn ati ajinigbe fi n ṣe ibuba, ti wọn maa n sa si ki wọn too kọlu awọn eeyan.
Ohun ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ sọ ree
Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adewale Osifẹsọ fi sita lori iṣẹlẹ yii, o ni ahesọ ọrọ lasan lohun to gbode lori ayelujara.
Osifẹsọ sọ pe ẹnikẹni ko ku ninu ikọlu yii, o ni awọn to farapa si ti n gba itọju nile iwosan.
Alukoro ọlọpaa rọ awọn araalu lati ma ṣe kaya soke lori iṣẹlẹ yii, ki wọn ma si ṣe gba ahesọ ori ayelujara gbọ.
O fi kun un pe eto aabo ti nipọn si i lawọn agbegbe yii, bẹẹ ni iṣẹ n lọ lori rẹ lati tubọ so okun aabo le si i.
Bi ẹnikẹni ba ni ohunkohun lati sọ ti yoo ran eto aabo lọwọ lori iṣẹlẹ yii tabi omi-in, Osifeso ni ki wọn fi to ileeṣẹ leti.
Ileeṣẹ ọlọpaa Ọyọ wa ṣeleri lati maa fi bi ohun gbogbo ba ṣe n lọ si lori ijamba naa to araalu leti.















