Aláboyún kan láti Naijiria bímọ sí Hajj nílùú Makkah

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Obìnrin kan lara awọn to lọ si Hajj ọdun 2023 lati Naijiria, ti bímọ silu Mecca. Ileesẹ eto ilera orile-ede Saudi Arabia sọ pe obìnrin naa ni ẹni àkọ́kọ́ to bímọ ni Hajj 2023 lai ṣe iṣẹ́ abẹ. Ileewosan ìgbẹ̀bí ati itọju ọmọdé niluu Makkah ni obìnrin naa bímọ si lasiko ti iṣẹ́ Hajj de oju ami lọjọbọ. Ninu atẹjade ti wọn fi sita, ọkùnrin ni ọmọ naa, eyi ti wọn ti sọ orúkọ rẹ ni Abdul Rahman. Àwọn aláṣẹ ní lọ́dọọdún ni iléèwòsàn naa ma n gbalejo awọn obinrin to fẹ́ bímọ lasiko Hajj. Lara ilana irinajo Hajj ni pe alaboyun ko gbọdọ kopa, eyi lo si mu ki àjọ to n mojuto eto naa ni Naijiria, NAHCON, ma a ṣe ayẹwo oyun fun awọn obinrin ki wọn to gba iwe ìrìnnà fun wọn. Sugbọn ṣá, àjọ naa ni obìnrin alaboyun marundinlọgọrin lo gba ọna ẹ̀bùrú wọ Saudi Arabia fun Hajj lai ṣe ayẹwo oyún. Olori ikọ eto ilera fun NAHCON, Dokita Usman Galadima sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ni Makkah pe wọn kii faaye gba àwọn alaboyun ni Hajj lati dena wahala airo tẹ́lẹ̀ to le ba wọn nitori bi oorun to mú jù ni Saudi, ati àwọn iṣẹ́ Hajj to lágbára lati ṣe.
Ọ̀kan lára òpó márùn-ún tó gbé ẹ̀sìn Islam ró ni lílọ sí Hajj jẹ́.
Ohun ni opo karùn-ún èyí tó kẹ́yìn nínú òpó tí ẹni tó bá jẹ́ Mùsùlùmí gbọ́dọ̀ tẹ̀lé tó sì jẹ́ dandan fún gbogbo Mùsùlùmí.
Ní ìlú Mecca ní orílẹ̀ èdè Saudi Arabia ni Hajj ṣíṣe ti máa ń wáyé ní ọdọọdún tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Mùsùlùmí káàkiri orílẹ̀ èdè àgbáyé sì máa ń péjọ sí láti ṣe ìjọ́sìn wọn.
Hajj ṣíṣe pọn jẹ́ ọ̀ranyàn fún Mùsùlùmí lọ́kùnrin àti obìnrin tó bá ti bàlágà (dàgbà), tó ní owó lọ́wọ́, tó sì tún ní àlàáfíà pípé láti lọ ní ẹ̀ẹ̀kan.
Lílọ sí Hajj ju ìgbà ẹyọ̀kan lọ kìí ṣe ohun tó burú rárá níwọ̀nba ìgbà tí ènìyàn bá ní owó rẹ̀ lọ́wọ́ tí àláfíà rẹ̀ náà sì pé pérépéré.
Ìgbàgbọ́ àwọn Mùsùlùmí ni pé tí ènìyàn bá ṣe iṣẹ́ Hajj gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ nínú ìwé mímọ́ Àlìkùránì, gbogbo nǹkan tí àwọn bá béèrè fún ní Hajj ló máa wá sí ìmúṣẹ àti pé gbogbo ṣẹ̀ṣẹ̀ tó bá ní lọ́rùn ni Ọlọ́run máa parẹ́ fun.
Ṣíṣe Hajj jẹ́ ohun iduunu fún àwọn Mùsùlùmí tó sì tún máa ń jẹ́ àsìkò tí wọ́n ní láti fi sún mọ́ Ọlọ́run.












