Lónìí ni ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yóò dájọ́ tí Rhodes-Vivour LP àti Jandor PDP pe Sanwo-Olu pé kò wọlé ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko

Aworan Rhodes-Vivour, SAnwo-Olu ati Jandor

Oríṣun àwòrán, Facebook

Lonii Ọjọru ọjọ kẹẹdogun oṣu kọkanla ni ile ẹjọ kotẹmilọrun yoo dajọ ti oludije fun ipo gomina ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Gbadebo Rhodes-Vivour ati oludije fun ipo gomina ẹgbẹ Peoples Democratic Party, PDP, Abdulazeez Olajide Adediran pe gomina Babajide Sanwo-Olu pe ko wọle ibo gomina ipinlẹ Eko.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Eko ti kede pe ago mẹta ọsan oni Ọjọru ni idajọ naa yoo waye.

Ni bii ọsẹ kan sẹyin lọjọ keje oṣu kọkanla yii naa ni adajọ Yargata Nimpar atawọn akẹgbẹ rẹ sun idajọ sọjọ kẹẹdogun oṣu yii.

Awọn adajọ mii to n joko lori ẹjọ ọhun ni adajọ Samuel Bola ati adajọ Paul Bassi.

Ẹwẹ, lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹsan an ọdun yii ni ile ẹjọ to n ri si awuyewuye to jẹyọ lori ibo gomina ipinlẹ Eko fontẹ lu Sanwo-Olu pe oun lo wọle ibo gomina ipinlẹ naa.

Lẹyin naa ni agbẹjọro Rhodes-Vivour pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa.

Bakan naa ni oludije ẹgbẹ PDP ti ọpọ eeyan mọ si Jandor pe ẹjọ kotẹmilọrun onikoko mẹrinlelọgbọn tako iyege Sanwo-Olu ninu ibo gomina ipinlẹ Eko.

Jandor tun beere lọwọ ile ẹjọ wi pe ko wọgile oludije fun ipo gomina ẹgbẹ oṣelu APC ati LP.