Ìyanṣẹ́lódì ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà mú ìfàsẹ́yìn bá ìgbẹ́jọ́ Tani Olohun

Aworan Tani Ọlọhun ati ile ẹjọ

Iyanṣẹlodi ẹgbẹ oṣiṣẹ to waye lorilẹede Naijiria ti mu ifasẹyin ba igbẹjọ lori gbigba beeli gbajugbaju ajafẹtọ ẹsin abalaye, Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mo si Tani Ọlọhun niwaju ile ẹjọ Majisireeti kan ni ilu Ilọrin, olu ilu ipinlẹ Kwara lẹkun aringbungbun ariwa Naijiria.

Lara awọn ẹjọ ti o wa lọrun Tani Ọlọhun ni eyi ti awọn ẹgbẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ ẹgbẹ Modrasatu Mohammed fi kan an pe o dana sun Kurani.

Tani Ọlọhun n rawọ ẹbẹ si ile ẹjọ naa fun beeli lori ẹjọ naa, eyi to tun ba ijakulẹ pade lọjọ Iṣẹgun nitori iyanṣẹlodi awọn ioṣiṣẹ to bẹrẹ ni Naijiria.

Awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria n yanṣẹlodi lati fi ẹhonu han fun bi awọn janduku kan ṣe din dundu iya fun aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ni ipinlẹ Imo loṣu kẹwaa.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ n na ina si gomina ipinlẹ Imo atawọn oṣiṣẹ rẹ kan pe awọn lo wa ni idi iklu naa.

Amọ igbẹjọ ẹbẹ beeli lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan Tani Ọlọhun tẹsiwaju

Ẹwẹ, ile ẹjọ naa tun gbọ ẹjọ miran to da lori ẹsun mii to da lori ibanilorukọ jẹ ti wọn fi kan Tani Ọlọhun kan naa.

Agbẹjọro to n duro fun un, Ademola Banks lo kọ iwe ẹbẹ fun beeli fun un lẹyin to ti lo ọjọ metadinlaadorun ni ahamo ijọba.

O ni ko si atako si ẹbẹ beeli naa ati gbigba oniduro afurasi ọhun nitori eto tubi n nubi to n lọ lọwọ laarin olupẹjọ ati olujẹjọ.

Ninu idahun rẹ, agbẹjọro fun Sheikh Labeeb Lagbaji to jẹ olupẹjọ, Kayode Olateju sọ pe boya ohun tako ẹbẹ fun beeli ọhun tabi ohun o tako o, adajọ lo mo ohun to tọ lati se.

Olateju salaye pe ohun to le lori ọrọ naa ni wi pe ibi ti olujẹjọ ọhun n gbe kii se arọwọto ile ẹjọ, ko si dara ko gba ominira tan ko wa salọ.

Lẹyin awuyewuye awọn mejeji yii, adajọ Muhammed Adam sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlogun osu ti a wa yii.