Wo ìdí tí Godwin Emefiele, gómìnà báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, yóò fi ṣe ọdún Kérésìmesì ní àtìmọ́lé

Aworan Godwin Emefiele

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina banki apapọ tẹlẹ, Godwin Emefiele yoo ṣe ayẹyẹ ọdun keresimesi ati ọdun tuntun ni ahamọ.

Eyi ko sẹyin bi o ṣe kuna lati ri baali gba lọjọ Isẹgun, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2023.

Bẹẹ ba gbagbe ninu oṣu kẹjọ ni Ajọ EFCC kọkọ fẹsun kan Emefiele. arábìnrin Saadatu Yaro ati ileeṣẹ April 1616 to jẹ ileeṣẹ arabinrin Yaro lori ẹsun pe wọn ra awọn ọkọ ayọkẹlẹ kan ni ilana to lodi si ofin.

Igbẹjọ ko waye lasiko naa nitori bí kudiẹkudiẹ ṣe ba ìlera Yaro.

Ẹsun ìwa ajẹbanu lasìko to wa nípo gẹgẹ bí gomìna CBN ni Emefiele n kojú.

Ẹsun ogun tí apapọ owo rẹ jẹ bílíọnu mẹfà le ọwọ marun-ún naíra ni ìjọba apapọ kọkọ ka sí Emefiele lọrùn lati kojú ìgbẹjọ le lórí.

Amọ ìjọba apapọ ti mu àdínkù bá iye ẹ̀sùn náà sí mẹfà tí owó rẹ sì lé bilíọnu kan naira ni ileẹjọ lọjọ Ẹtì.

Ki lo sẹlẹ saaju?

Saaju ni wọn igbẹjọ rọ lori ẹsun iwa ajẹbanu oni biliọnu mẹfa ati ẹẹdẹgbẹrun miliọnu Naira (N6.9 billion) ti ijọba apapọ fi n kan gomina agba tẹlẹ fun Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele niwaju ile ẹjọ giga apapọ nilu Abuja.

Emefiele ti wa ni ahamọ awọn agbofinro DSS lati igba ti aarẹ Naijiria, Bọla Tinubu ti paṣẹ ko lọ rọọkun nile ni ọjọ kẹsan oṣu kẹfa ọdun 2023.

Ẹsun ti wọn n fi kan an ni pe o lo ipo rẹ lati fun Yaro to jẹ oludari ni ileeṣẹ naa lawọn anfani ti ko tọna labẹ ofin.

Iwe ẹsun ti ileeṣẹ eto idajọ gbe ka iwaju ile ẹjọ naa sọ pe, ọkọ ayọkẹlẹ mejidinlọgọrun atawọn ọkọ ayẹta ti owo rẹ to biliọnu mẹfa ati ẹẹdẹgbẹrun miliọnu Naira (N6.9 billion).