EFCC ṣàlàyé ọ̀nà mẹ́jọ tí o lè fi dènà àwọn tó bá fẹ́ fi ATM àti POS wọ́ owó lọ nínú àkáǹtì rẹ

Oríṣun àwòrán, getty images
Ẹnu ọjọ mẹta yii ni ọpọ eeyan kaakiri Naijiria bẹrẹ si n ke gbajare nipa bi awọn kọlọrọsi kan ṣe n wọ owo lọ ninu apo ifowopamọ wọn.
Ọpọ eeyan lo maa n ṣakiyesi pe obitibiti owo n poora ninu banki wọn lai ra ohunkohun tabi lo kaadi ATM wọn lati san owo.
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC sọ pe awọn iwa jibiti yii maa n waye ti ọwọ awọn kọlọrọsi ẹda naa ba ti tẹ kaadi ATM eeyan.
Amọ ki ni o le ṣe lati daabo bo ara rẹ lọwọ irufẹ jibiti bẹẹ tabi ti kaadi ATM rẹ ba sọnu?
Ninu atẹjade kan ti EFCC fi lede loju opo X, o ṣalaye awọn ohun ti eeyan le ṣe lati daabo bo ara, paapaa kaadi ATM rẹ.
Bi awọn onijibiti ṣe le ji kaadi ATM ati PIN rẹ
EFCC ṣalaye pe asiko ti eeyan n gba owo lẹnu ẹrọ ATM tabi POS ni wọn ti maa n ji kaadi ATM ju.
Gẹgẹ bii ohun ti EFCC sọ, awọn to n ji ATM eeyan maa ni irufẹ kaadi eeyan lọwọ ti wọn a si tete paarọ rẹ nibi ti eeyan ba ti fẹ gba owo lẹnu ẹrọ ATM lẹyin ti wọn ba dibọn pe awọn fẹ ran irufẹ ẹni bẹẹ lọwọ lati gba owo.
EFCC ni ti wọn ba ti yara paarọ kaadi ẹni ti wọn fẹ wọ owo rẹ lọ, ẹrọ ATM ọhun yoo gbe kaadi irufẹ ẹni bẹẹ mi latari pe nọmba ‘PIN’ rẹ ko ba kaadi to wa ninu ẹrọ ATM ṣiṣẹ.
Lẹyin ti onibara ti wọn paarọ kaadi rẹ ba lọ tan lati lọ wa ọna ti yoo fi ri kaadi naa yọ ni awọn kọlọrọsi ọhun yoo gba gbogbo owo to wa ninu apo iṣuna ẹni naa tan.
Ọna ati dẹkun iwa jibiti wọnyi
EFCC ṣalaye awọn nnkan mẹjọ ti eeyan le ṣe lati dẹkun jiji kaadi ATM eeyan ati wiwọ owo ninu apo iṣuna ẹni, awọn ọna ọhun ree.
- Maa fi kaadi ATM rẹ si ibi ti oju rẹ yoo to, si ri daju pe kaadi ATM rẹ ni wọn fun ọ pada ti o ba lo kadi naa lati gba tabi san owo ni POS
- Ri daju pe o n wo ‘bank statements’ rẹ loorekoore lati ṣawari awọn owo to jade nibẹ ti o ko mọ nipa rẹ
- Ri daju pe o n gba atẹjiṣe ni gbogbo igba ti owo ba wọle tabi jade ninu apo iṣuna rẹ
- Fi ọwọ bo nọmba PIN rẹ ti o ba n lo kaadi rẹ nidi ẹrọ ATM tabi POS
- Maṣe kanju lati san owo tabi gba owo, si maa kan si banki rẹ nikan ṣoṣo ti o ba dojukọ iṣoro lori apo iṣuna rẹ
- Pe banki rẹ ki wọn dina kaadi ATM rẹ ni igbakugba to ba ha si ẹnu ẹrọ ATM
- Ri daju pe o mọ awọn nọmba ti o le fi dina kaadi ATM rẹ funra rẹ ti o ba sọnu tabi ha sẹnu ẹrọ
- Tẹ nọmba *966*911# lati dina kaadi ATM rẹ lẹsẹkẹsẹ ti o ba sọnu lọwọ rẹ














