Toyinbo rèé, ọlọ́kadà tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè pẹ̀lú ‘First Class’ ní fásitì FUNAAB
Toyinbo rèé, ọlọ́kadà tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè pẹ̀lú ‘First Class’ ní fásitì FUNAAB

Oríṣun àwòrán, Toyinbo Ojuọla
Toyinbo Hezekiah Ojuọla jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ to kẹkọ̀gboye ni fasiti ẹkọṣẹ imọ nipa eto ọgbin FUNAAB to wa nilu Abẹokuta laipẹ yii.
Ohun to mu ki Toyinbo di ẹni ti ọpọ obi nibi eto naa ati lẹyin eto naa o kan saara sii ni

Oríṣun àwòrán, Toyinbo Ojuọla
O ni erongba awọn obi oun ni pe ki oun kọṣẹ lẹyin to pari ẹkọ girama ṣugbọn ipinnu ọkan rẹ lo mu ki o pinnu lati tẹsiwaju ẹkọ.

Oríṣun àwòrán, Toyinbo Ojuọla
Bakan naa lo fi kun un pe ọpọ awọn akẹgbẹ oun ni ilu Ipokia ti oun ti wa ni wọn ti gba ọna igbeyawo lọ.
Toyinbo ni ọpọlọpọ iṣẹ ọwọ bii birisope, ọkada wiwa ati bẹẹbẹlọ loun ṣe lati fi ran ara oun lọ si ile ẹkọ.






