Ìjọba Ekiti pe pásítọ̀ Chef Dammy lẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìdúnkokòmọ́ni, bèrè ₦10m owó gbá máb̀inú lọ́wọ́ rẹ̀

Chef Dammy

Oríṣun àwòrán, @yabaleftonline

Ajọ to n ja fun ẹtọ araalu nipinlẹ Ekiti, Directorate of Citizens Rights, DCR, ti pe ẹjọ kan loruko Adeparusi Damilola ti ọpọ eeyan mọ si Chef Dammy tako pasitọ rẹ, Jeremiah Adegoke ati ileeṣẹ ọlọpaa.

Eredi ipẹjọ naa ko ṣẹyin pe pasitọ ọhun atawọn ọlọpaa tẹ ẹtọ akẹkọọbinrin naa loju mọlẹ.

DCR tun n bere fun miliọnu mẹwaa naira owo gba mabinu fun Chef Dammy to jẹ akẹkọọ nipa iṣẹ akọroyin ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Oye Ekiti.

Ajọ naa tun bẹ ile ẹjọ lowẹ ko dẹkun pasitọ Adegoke ati ileeṣẹ ọlọpaa lati fi ofin gbe ọdọbinrin ọhun.

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin iroyin to ni pasitọ naa fi ọlọpaa gbe Dammy lorin ẹsun ibanilorukọjẹ.

Ki lo fa gbas-gbos laarin Chef Dammy ati pastitọ rẹ?

Wahala bẹrẹ laarin awọn mejeji ninu oṣu Kẹwaa lẹyin ti akẹkọọ naa ke gbajare pe awọn kan to pe ara wọn ni ‘eeyan Ọlọrun’ ati pasitọ naa n dunkoko mọ oun.

Damilola fẹsun kan pasitọ Adegoke pe o n halẹ mọ oun.

Ẹwẹ, pasitọ Adegoke, lati ọwọ awọn agbẹjọro rẹ kọ lẹta si Damilola pe ko tọrọ aforijin lọwọ oun ninu iwe iroyin fun pe o ba oun lorukọ jẹ.

DPR

Oríṣun àwòrán, @ekititrends

DPR

Oríṣun àwòrán, @ekititrends

Pasitọ naa tun ni Damilola gbọdọ san owo ti iye rẹ to miliọnu mejilelogun naira fun oun gẹgẹ bii owo gba mabinu fun bo ṣe n jẹ orukọ oun lẹnu.

Adegoke fun Dammy ni ọjọ meje pere lati ṣe ohun ti oun n bere tabi ko foju bale ẹjọ.

Wayi o, ninu iwe ipẹjọ ti DPR pe lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, orukọ Dammy lo wa ni orukọ olupẹjọ, ti pasitọ Adegoke, kọmiṣọna ọlọpaa ati igbakeji ọga ọlọpaa AIG Zone 17, Akure si jẹ olujẹjọ.

Lara ẹsun ti DPR fi kan awọn olujẹjọ naa ni idunkokomọni, ihalẹmọni lati ọwọ pasitọ atawọn ọlọpaa ati titẹ ẹtọ akẹkọọ naa loju mọlẹ.

Inu oṣu Kẹfa, ọdun 2023 ni irawọ Chef Dammy milẹ titi lẹyin to se ounje fun ọpọ wakati.