Obìnrin tó da omi gbígbóná lé ọkọ rẹ̀ lórí ẹ̀sùn pé ó ń yàn àlè yóò ṣe kérésì ní àtìmọ́lé

Hot water

Oríṣun àwòrán, X @Thehilariousope

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi ṣikun ofin mu iyawo ile kan, Dorcas Oluwabukola, lori ẹsun pe o da omi gbigbona le ọkọ rẹ lori.

Agbegbe Meiran ni iṣẹlẹ naa ti way lẹyin ti afurasi ọhun fẹsun kan kọ ọkunrin naa pe o n yan ale.

Ileeṣẹ iroyin abẹle Punch jabọ pe ọlọpaa kan ni agọ to wa ni Meiran, amọ ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede sọ pe awọn yoo gbe afurasi naa lọ si ẹka CID lẹyin iwadii.

Iroyin ni wahala bẹrẹ laarin tọkọ-taya ọhun lẹyin ti ọkọ obinrin naa lọ sibi ayẹyẹ igbeyawo kan amo ti ko mu afurasi ọhun dani.

A gbọ pe ọrọ naa lo fa ede aiyede laarin wọn, ki iyawo to da omi gbigbona le ọkọ rẹ lori.

Ọlọpaa ni idajọ ododo yoo waye lori ọrọ naa, awọn si n bojuto ilera ọkọ obinrin ọhun to ti wa nile iwosan lati igba ti isẹlẹ naa ti waye.

Ọlọpaa naa ni “Lootọ ni iṣẹlẹ ọhun waye... o da omi gbigbona lori ọkọ rẹ lori lẹyin to ro pe o n fẹ ẹlomiran lẹyin oun.

“O yẹ ki wọn jọ lọ si ode ariya kan ni amọ ọkọ rẹ da nikan lọ.

“Ọkunrun naa ṣi wa nile iwosan lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye, ko tii pada sile lati ibi ti wọn ti n tọju rẹ.

“Ni kete ti a gbọ ni a fi ṣikun ofin mu afurasi naa nitori iwa ọdaran nla lo wu, ko si si aye lati gba beeli rẹ, a n duro de asiko ti a maa gba lọ si ẹka CID”

Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin ko tii sọ ohunkohun lori iṣelẹ naa.