Wo ìdí tí ìgbésẹ Lasepa láti ti ilé ìtura Quilox pa làìsùn ọdún kò ṣe jọ́ aráàlú lójú

Oríṣun àwòrán, LASEPA/Twitter
Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe ẹnu ọna abawọle ile ìtura Quilox ti pa laisun ọdun Keresimesi.
Wọn ní awọn sọ agadagodo sẹnu ọna wọn tori pe wọn tapa sofin imojuto ayika.
Lọjọ Aiku tii ṣe aisun ọdun Keresimesi ni wọn gbe igbesẹ yi.
Ile itura ati aaye igbafẹ yi to wa lagbegbe Ozumba Mbadiwe Road,Victoria Island nilu Eko jẹ ti gbajugbaja oloṣelu nii Shina Peller.
Ajọ to n mojuto ayika ati ajọ to n risi idaabo araalu LASEPA ati LSC lo jijọ pawọpọ gbe ẹnu ọna Quilox ti pa.
Loju opo LASEPA wọn fi ikede yi sibẹ ti wọn si fi alaye ohun to ṣokunfa titi pa yi naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Yatọ si eyi Lasepa fi ikilọ sita fawọn aaye igbafẹ mii to wa lagbegbe naa pe ki wọn mojuto ayika wọn ki iru nkan to ṣẹlẹ sí Quilox ma ṣe ba awọn naa.
Sol Beach ati Landmark Beach ni awọn mii tí wọn kìlọ fun pe k'awọn naa ṣe pẹlẹ lori ọrọ alaafia ati ayika wọn.
Agbegbe t'awọn ile igbafẹ yi wa a maa koju sunkere-gbakere ni asiko ọdun ti ẹsẹ kii si gbero níbẹ rara
Lasepa ati LSA sọ pe kii ṣe igba akọkọ ree t'awọn yoo kìlọ fun Quilox pe ko wa nkan ṣe si lilọ bibọ ero ni ile igbafẹ rẹ.
Odu ni Quilox nibi ki ijọba maa ti ilẹ ìtura rẹ pa
Igba akọkọ kọ ni yi ti ẹka ileeṣẹ ìjọba to n mojuto ayika yoo kéde titi pa Quilox.
Lọdun to kọja lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kejila wọn ti ile itura yi pa tori idiwọ to fa fun lilọ bibọ ọkọ.
Loṣu Kọkànlá ọdun 2023 yi wọn gbe Quilox ti pa lori itapa sofin.
Iru nkan bayii tun waye lọdun 2019 ati 2022.
Ni gbogbo igba to ba waye ileeṣẹ ìjọba naa a maa pada tun sọ pe awọn ti si ile igbafẹ naa pada leyin to seleri lati tẹle ilana to de ayika rẹ.

Oríṣun àwòrán, Tribune Online

Oríṣun àwòrán, TheCable
Loju opo Twitter awọn eeyan ti n sọ pe igbesẹ yi ko le so eso ree tori pe wọn yoo tun si ile itura naa pada.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2












