Ìjọba tú ẹlẹ́wọ̀n tó lé ní 1,000 sílẹ̀ láti ṣàjọyọ̀ ọdún Keresimesi

Prison

Oríṣun àwòrán, getty images

Aarẹ Sri Lanka, Ranil Wickremesinghe, ti tu ẹlẹwọn to le ni ẹgbẹrun kan silẹ ni ahamọ lati sami si ayẹyẹ ọdun keresimesi.

Apapọ iye awọn ẹlẹwọn naa jẹ ẹgbẹrun kan ati eeeyan mẹrin.

Lara awọn eeyan naa lo dero ọgba ẹwọn latari pe wọn ko le san awọn owo itanra kan, gẹgẹ bii ohun ti oludari ọgba ẹwọn ilẹ naa, Gamini Dissanayake, sọ.

Pupọ awọn eeyan to wa lorilẹ-ede Sri Lanka lo jẹ ẹlẹsin Buddha, eyii to mu ki ijọba ilẹ ọhun ṣe irufẹ nnkan bayii lasiko ọdun Vesak ninu oṣu Karun un ọdun yii lati sami si ayẹyẹ ọjọ ibi Buddha, ẹkọ ati iku rẹ.

Itusilẹ awọn ẹlẹwọn tuntun yii lo n waye lẹyin ti ọlọpaa fi ṣikun ofin mu nnkan bii ẹgbẹrun marundinlogun eeyan laipẹ yii.

Ọgọ ero naa ko si ahamọ awọn ologun lori ẹsun gbigbe oogun oloro.

Ọpọ ọjọ ni awọn ologun fi n ko awọn afurasi ni igboro ki wọn to dawọ rẹ duro lọjọ aisun ọdun Keresimesi.

Atẹjade kan lati ọọfisi ọlọpaa sọ pe eeyan 13,666 ni ọwọ tẹ lori ẹsun gbigbe oogun oloro, nigba ti wọn mu eeyan 1,100 mii fun lilo oogun naa, ki wọn to ko gbogbo wọn si atimọle.

Ni ṣe ni ọgba ẹwọn maa n kun akunfaya ni Sri Lanka.

Gẹgẹ bii akọsilẹ, nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọgbọn eeyan lo wa ninu ọgab ẹwọn ti wọn kọ fun ẹgbẹrun mọkanla eeyan kaakiri orilẹ-ede ọhun.