Israel Gaza war: Hamas sọ pé èèyàn 70 kàgbákò ikú lọ́wọ́ àdó olóró tí Israeli ju lù wọn

Àkọlé fídíò, Wọn gbe awọn to farapa lọ si ile iwosan Al-aqsa
    • Author, Shaimaa Khalil in Jerusalem and Youssef Taha in London
    • Role, BBC News

Ileeṣẹ ilera Gaza sọ pe ado oloro kan ti Israeli sọ ti ṣekupa eeyan aadọrin ni ibudo Al-Maghazi tawọn ogunlende fori pamọ si.

Agbẹnusọ wọn kan sọ pe o ṣeeṣe ki iye awọn to ku lekun si tori aduru mọlẹbi to n gbe ni ibudo naa.

Ileeṣẹ ologun Israel sọ fun BBC pe awọn n ṣe iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Ikọlu yi n waye lasiko ti Egypt to mule ti Gaza ti ṣe agbekalẹ ilana tuntun ti yoo mu ki wọn dawọ ija duro laarin Israel ati Hamas.

Ọkẹ aimọye eeyan lo farapa ti wọn si gbe wọn lọ sileewosan Al-Aqsa ti a si ri fọnran fidio to ṣafihan awọn oku ti wọn gbe sinu apo ati awọn ọmọde ti ẹjẹ bo oju wọn.

Ileeṣẹ ilera tun sọ pe ile mẹta kan farapa ninu ikọlu yi to waye lọjọ Aiku.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ ilera Ashraf al-Qudr ṣe sọ agbegbe kan tawọn eeyan pọ si ni ikọlu naa parẹ patapata.

Awọn eeyan niile iwosan Al-Aqsalẹyin ikọlu to waye

Oríṣun àwòrán, AP

Baba kan sọ pe oun padanu ọmọ rẹ obinrin ati awọn ọmọ ọmọ rẹ to si fikun pe awọn sa kuro lapa ariwa wa si aarin gbungbun Gaza ni.

O ni ''aja kẹta ile wa ni wọn n gbe'' O fikun pe ''Niṣe logiri ile ya lu wọn.Awọn ọmọ ọmọ mi, ọmọ mi obinrin, ọkọ rẹ, gbogbo wọn ti ku''

''Wọn mọọmọ doju ija kọ wa ni.Awa araalu. Ko si ibi ti ko si ewu nibẹ.Wọn sọ pe ki a fi ilu Gaza silẹ- a ti wa si aarin gbungbun Gaza bayii lati wa kagbako iku''

Ajọ alagbelebu pupa sọ pe ''ikọlu kikan kikan ti mu ki wọn ti opopona laarin ibudo Maghazi ati awọn ibudo atipo mii,Al-Bureij ati Al-Nuseirat''

Eyi a si maa fa idiwọ fawọn oṣiṣẹ adoola ati ọkọ ti wn yoo fi gbe alaisan.

Ninu atẹjade ti wọn fi ṣọwọ si BBC, ileeṣẹ ologun Israel sọ pe awọn ko gburo ikọlu kankan ni ibudo Maghazi.

Wọn ni ''tohun ti gbogbo iṣoro taa n koju lọwọ awọn agbesunmọmi Hamas to wa laarin awọn agbegbe taraalu n gbe ni Gaza, ileeṣẹ ologun Israel ko sọ ireti nu lati gbe igbese ti yoo mu adinku ba ifarapa awọn araalu''

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ilera ti ṣe sọ o le ni eeyan ọgrun lọna ogun ti wọn ti pa-ọpọ ninu wọn jẹ ọmọde ati obinrin-tawọn ẹgbẹrun lọna marun le laadọta si farapa ni Gaza lati ọjọ Keje oṣu Kẹwaa.

Eyi waye lẹyin ti Hamas ati awọn ikọ Palestine mii ṣe ikọlu si Israel ti wọn si pa eeyan ẹgbẹfa ti wọn si ko awọn ojilerugba lẹru.

Lọjọ Aiku Olootu ijọba Israel Benjamin Netanyahu sọ pe ogun tawọn n ja yi wa pẹlu adanu nla.

Ileeṣẹ ologun Israel sọ pe o le ni ọmọ ogun awọn mejila to padanu ẹmi wọn ni Gaza ti eyi si mu iye awọn to ku lẹyin ikọlu ọjọ Keje oṣu Kẹwaa di eeyan mẹrindinlọgọjọ.

Ọjọ Abamẹta jẹ ọkan lara awọn ọjọ ti ikọlu naa lagbara amọ ọgbẹni Netanyahu sọ pe ko si ṣiṣe ko si aiṣe ju kawọn tẹsiwaju pẹlu ogun naa,

Awọn oludaro to peju sibi isinku ọmọ ogun Israeli kan ni Haifa lọjọ Aiku

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aba tuntun ti Egypt n gbero lori dida ija duro la gbọ pe wọn yoo ṣe agbekalẹ rẹ lọna mẹta:

  • Akọkọ ni pe wọn yoo faaye ọjọ meje si mẹwaa ti Hamas yoo fi tu gbogbo awọn araalu ọmọ ilẹ Israel to wa lọdọ wọn ni paṣiparọ pẹlu awọn ẹlẹwọn Palestine to wa ni gba ẹwọn Israel.
  • Labẹ idawọ ija duro abala keji ti wn yoo fi ọsẹ kan ṣe, Hamas yoo tu gbogbo awọn ọmọ ogun obinrin Israelisilẹ lati fi paarọ pẹlu awọn ẹlẹwọn mii ati awọn oku ti Israel diwọ mọ lati ọjọ Keje oṣu Kẹwaa
  • Abala kẹtaa ni wọn yoo fi tu awọn ti o wa ni ahamọ Hamsa yoku silẹ ni paṣipar pẹlu awn ọmọ Palestinine to wa lẹwọn ti Israel yoo si ko awọn ọmọ ogun kuro ni Gaza ti baalu ko si ni fo kja lagbegbe naa mọ.

Egypt ni ijiroro yoo ti waye tiQatar ati America naa yoo si kopa.

Oṣiṣẹ Israel kan sọ fun ileeṣẹ iwe iroyin Maariv pe akitiyan Egypt yi le yọri si idunadura.

Hamas sọ pe awọn n ṣe agbeyẹwo aba ti wn mu wa yii.

Ẹwẹ ileeṣẹ to n kẹru gba ori mi ilẹ Denmark nii, Maersk sọ pe awọn n palẹmọ lati bẹrẹ iṣẹ pada gba okun pupa kọja si Gulf of Aden

Ikede yi waye lẹyin ti wọn se agbekalẹ ikọ ologun agbaye kan ti America lewaju rẹ lati koju idojule awọn kọntena to n gbẹru kọja lati ọwọ awọn ọmọ ogun ọlọtẹ Houthi.,

Awọn ikọ Houthi yi ti jẹjẹ atilẹyin fun Hamas ti wọn si lawọn ko ni faaye gba ọkọ oju omi kankan lati kẹru lọ si Israel.

Maersk ati awọn ileeṣẹ ọkọ oju omi mii dawọ kikẹru gba omi okun Pupa ati Suez Canal nibẹrẹ oṣu yi tori ikọlu lọwọ awọn diroonu.

Ileeṣẹ ologun America lagbegbe naa s pe awọn ja diroonu mẹrin kan lulẹ lagbegbe omi okun pupa eyi ti wọn ran wa lati agbegbe Yemen.

Bakan anaa, Poopu mimọ Pope Francis ti pe fun alaafioa lagbegbe ilẹ larubawa lasiko to n dari ijọsin aisun Kersimesi to waye ni Saint Peter's Basilica ni Vatican.

O mẹnu ba ogun to nwaye laarin Israel ati Hamas to si ni ọrọ alaafia ti Jesu fi ranṣẹ ni gbogbo alaye ti ko bojumu lori ogun yi ti n tẹri ni ilẹ ti wọn bi Jesu si.

Pope mimọ laisun ọdun Keresimesi

Oríṣun àwòrán, Reuters

Afikun iroyin lati ọwọ awọn akọroyin BBC